1 Bí mo tún ti gbé ojú sókè, mo rí ọkunrin kan tí ó mú okùn ìwọ̀n lọ́wọ́.
2 Mo bi í pé, “Níbo ni ò ń lọ?” Ó bá dáhùn pé, “Mò ń lọ wọn Jerusalẹmu, kí n lè mọ òòró ati ìbú rẹ̀ ni.”
3 Angẹli tí ń bá mi sọ̀rọ̀ bá bọ́ siwaju, angẹli mìíràn sì lọ pàdé rẹ̀, Angẹli àkọ́kọ́ sọ fún ekeji pé,
4 “Sáré lọ sọ fún ọmọkunrin tí ó ní okùn ìwọ̀n lọ́wọ́ pé, eniyan ati ẹran ọ̀sìn yóo pọ̀ ní Jerusalẹmu tóbẹ́ẹ̀ tí a kò ní lè mọ odi yí i ká.