11 Ìwọ ní tìrẹ, nítorí ẹ̀jẹ̀ tí mo fi bá ọ dá majẹmu,n óo dá àwọn eniyan rẹ tí a kó lẹ́rú sílẹ̀ láti inú kànga tí kò lómi.
12 Ẹ pada sí ibi ààbò yín,ẹ̀yin tí a kó lẹ́rú lọ tí ẹ sì ní ìrètí;mo ṣèlérí lónìí pé,n óo dá ibukun yín pada ní ìlọ́po meji.
13 Nítorí mo ti tẹ Juda bí ọrun mi,mo sì ti fi Efuraimu ṣe ọfà rẹ̀.Ìwọ Sioni, n óo lo àwọn ọmọ rẹ bí idà,láti pa àwọn ará Giriki run,n óo sì fi tagbára tagbára lò yínbí idà àwọn jagunjagun.
14 OLUWA yóo fara han àwọn eniyan rẹ̀,yóo ta ọfà rẹ̀ bíi mànàmáná.OLUWA Ọlọrun yóo fọn fèrè ogunyóo sì rìn ninu ìjì líle ti ìhà gúsù.
15 OLUWA àwọn ọmọ ogun yóo dáàbò bo àwọn eniyan rẹ̀.Wọn óo borí àwọn ọ̀tá wọn,wọn óo fi idà pa àwọn ọ̀tá wọn,ẹ̀jẹ̀ wọn yóo sì máa ṣàn bíi ti ẹran ìrúbọ,tí a dà sórí pẹpẹ,láti inú àwo tí wọ́n fi ń gbe ẹ̀jẹ̀ ẹran.
16 Ní ọjọ́ náà, OLUWA Ọlọrun wọn yóo gbà wọ́n,bí ìgbà tí olùṣọ́-aguntan bá gba àwọn aguntan rẹ̀.Wọn óo máa tàn ní ilẹ̀ rẹ̀,bí òkúta olówó iyebíye tíí tàn lára adé.
17 Báwo ni ilẹ̀ náà yóo ti dára tó, yóo sì ti lẹ́wà tó?Ọkà yóo sọ àwọn ọdọmọkunrin di alágbáraọtí waini titun yóo sì fún àwọn ọdọmọbinrin ní okun.