Sakaraya 9:7-13 BM

7 N óo gba ẹ̀jẹ̀ ati ohun ìríra kúrò ní ẹnu rẹ̀, àwọn tí yóo kù ninu wọn yóo di ti Ọlọrun wa; wọn yóo dàbí ìdílé kan ninu ẹ̀yà Juda, ìlú Ekironi yóo sì dàbí ìlú Jebusi.

8 Ṣugbọn n óo dáàbò bo ilé mi, kí ogun ọ̀tá má baà kọjá níbẹ̀; aninilára kò ní mú wọn sìn mọ́, nítorí nisinsinyii, èmi fúnra mi ti fi ojú rí ìyà tí àwọn eniyan mi ti jẹ.

9 Ẹ máa yọ̀, ẹ̀yin ará Sioni!Ẹ hó ìhó ayọ̀, ẹ̀yin ará Jerusalẹmu!Wò ó! Ọba yín ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ yín;ajagun-ṣẹ́gun ni,sibẹsibẹ ó jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, ó sì gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́,kódà, ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ni ó gùn.

10 OLUWA ní, òun óo kó kẹ̀kẹ́ ogun kúrò ní Efuraimu,òun óo kó ẹṣin ogun kúrò ní Jerusalẹmu,a óo sì ṣẹ́ ọfà ogun.Yóo fún àwọn orílẹ̀-èdè ní alaafia,ilẹ̀ ìjọba rẹ̀ yóo jẹ́ láti òkun dé òkunati láti odò Yufurate títí dé òpin ayé.

11 Ìwọ ní tìrẹ, nítorí ẹ̀jẹ̀ tí mo fi bá ọ dá majẹmu,n óo dá àwọn eniyan rẹ tí a kó lẹ́rú sílẹ̀ láti inú kànga tí kò lómi.

12 Ẹ pada sí ibi ààbò yín,ẹ̀yin tí a kó lẹ́rú lọ tí ẹ sì ní ìrètí;mo ṣèlérí lónìí pé,n óo dá ibukun yín pada ní ìlọ́po meji.

13 Nítorí mo ti tẹ Juda bí ọrun mi,mo sì ti fi Efuraimu ṣe ọfà rẹ̀.Ìwọ Sioni, n óo lo àwọn ọmọ rẹ bí idà,láti pa àwọn ará Giriki run,n óo sì fi tagbára tagbára lò yínbí idà àwọn jagunjagun.