2 Ẹ óo ṣá ti gbọ́ nípa iṣẹ́ tí Ọlọrun fi fún mi nípa oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀ láti ṣe fun yín.
3 Ọlọrun ni ó fi àṣírí yìí hàn mí lójú ìran, gẹ́gẹ́ bí mo ti kọ ọ́ sinu ìwé ní ṣókí tẹ́lẹ̀.
4 Nígbà tí ẹ bá kà á, ẹ óo rí i pé mo ní òye àṣírí Kristi,
5 tí Ọlọrun kò fihan àwọn ọmọ eniyan ní ìgbà àtijọ́, ṣugbọn tí ó fihan àwọn aposteli rẹ̀ mímọ́ ati àwọn wolii rẹ̀ nisinsinyii, ninu ẹ̀mí.
6 Àṣírí yìí ni pé àwọn tí kì í ṣe Juu ní anfaani láti pín ninu ogún pẹlu àwọn Juu, ara kan náà sì ni wọ́n pẹlu àwọn tí wọ́n jọ ní ìlérí ninu Kristi Jesu nípasẹ̀ ìyìn rere rẹ̀.
7 Èyí ni iṣẹ́ tí a fi fún mi nípa ẹ̀bùn oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ agbára rẹ̀.
8 Nítorí èmi tí mo kéré jùlọ ninu gbogbo àwọn onigbagbọ ni Ọlọrun fi oore-ọ̀fẹ́ yìí fún, pé kí n máa waasu fún àwọn tí kì í ṣe Juu nípa àwámárìídìí ọrọ̀ Kristi.