Efesu 5 BM

Gbígbé ninu Ìmọ́lẹ̀

1 Nítorí náà, gẹ́gẹ́ bí àyànfẹ́ ọmọ, ẹ fi ìwà jọ Ọlọrun.

2 Ẹ máa rìn ninu ìfẹ́ gẹ́gẹ́ bí Kristi ti fẹ́ wa, tí ó fi ara òun tìkararẹ̀ rú ẹbọ olóòórùn dídùn sí Ọlọrun nítorí tiwa.

3 Kí á má ṣe gbúròó ìwà àgbèrè, tabi oríṣìíríṣìí ìṣekúṣe, tabi ojúkòkòrò láàrin àwọn eniyan Ọlọrun.

4 Ìwà ìtìjú, ọ̀rọ̀ òmùgọ̀, tabi àwàdà burúkú kò yẹ yín. Kàkà bẹ́ẹ̀, ọpẹ́ sí Ọlọrun ni ó yẹ yín.

5 Ẹ̀yin alára mọ̀ dájú pé kò sí ẹnikẹ́ni tí ó ń ṣe àgbèrè, tabi tí ó ń ṣe ìṣekúṣe, tabi tí ó ní ojúkòkòrò, tabi tí ó ń bọ̀rìṣà, tí yóo ní ìpín ninu ìjọba Kristi, tíí ṣe ìjọba Ọlọrun.

Ìwà Ọmọ Ìmọ́lẹ̀

6 Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni fi ọ̀rọ̀ asán tàn yín jẹ. Nítorí irú èyí ni ibinu Ọlọrun fi ń bọ̀ wá sórí àwọn ọmọ aláìgbọràn.

7 Nítorí náà ẹ má ṣe fi ara wé wọn.

8 Nítorí nígbà kan, ninu òkùnkùn patapata ni ẹ wà. Ṣugbọn ní àkókò yìí ẹ ti bọ́ sinu ìmọ́lẹ̀ nítorí ẹ ti di ẹni Oluwa. Ẹ máa hùwà bí ọmọ ìmọ́lẹ̀.

9 Nítorí èso ìmọ́lẹ̀ ni oríṣìíríṣìí iṣẹ́ rere, òdodo ati òtítọ́.

10 Kí ẹ máa wádìí ohun tí yóo wu Oluwa.

11 Ẹ má ṣe bá àwọn tí ó ń ṣiṣẹ́ òkùnkùn tí kò léso rere kẹ́gbẹ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ máa bá wọn wí.

12 Nítorí àwọn ohun tí wọn ń ṣe níkọ̀kọ̀ tilẹ̀ ti eniyan lójú láti sọ.

13 Nítorí gbogbo nǹkan tí ìmọ́lẹ̀ bá tàn sí níí máa hàn kedere.

14 Ohun gbogbo tí ó bá hàn kedere di ìmọ́lẹ̀. Bí ọ̀rọ̀ orin kan ti sọ, pé,“Dìde, ìwọ tí ò ń sùn;jí dìde kúrò ninu òkú,Kristi yóo tan ìmọ́lẹ̀ sí ọ lára.”

15 Nítorí náà, ẹ ṣọ́ra bí ẹ ti ń hùwà. Ẹ má ṣe hùwà bí ẹni tí kò gbọ́n, ṣugbọn ẹ hùwà bí ọlọ́gbọ́n.

16 Ẹ lo gbogbo àkókò yín dáradára nítorí àkókò tí a wà yìí burú.

17 Nítorí náà, ẹ má ṣe jẹ́ aṣiwèrè, ṣugbọn kí ẹ máa fi òye gbé ohun tíí ṣe ìfẹ́ Oluwa.

18 Ẹ má máa mu ọtí yó, òfò ni. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ kún fún Ẹ̀mí Mímọ́.

19 Ẹ máa fi Orin Dafidi ati orin ìyìn ati orin àtọkànwá bá ara yín sọ̀rọ̀. Ẹ máa kọrin; ẹ máa fi ìyìn fún Oluwa ninu ọ̀kan yín.

20 Ẹ máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun Baba nígbà gbogbo fún gbogbo nǹkan ní orúkọ Oluwa wa Jesu Kristi.

Aya ati Ọkọ

21 Ẹ máa tẹríba fún ara yín nítorí ọ̀wọ̀ tí ẹ̀ ń bù fún Kristi.

22 Ẹ̀yin aya, ẹ máa tẹríba fún àwọn ọkọ yín gẹ́gẹ́ bí Oluwa.

23 Nítorí ọkọ ni olórí aya gẹ́gẹ́ bí Kristi ti jẹ́ olórí ìjọ. Kristi sì ni Olùgbàlà ara rẹ̀ tíí ṣe ìjọ.

24 Bí ìjọ ti ń bọ̀wọ̀ fún Kristi, bẹ́ẹ̀ ni kí àwọn aya máa ṣe sí àwọn ọkọ wọn ninu ohun gbogbo.

25 Ẹ̀yin ọkọ, ẹ fẹ́ràn àwọn aya yín, gẹ́gẹ́ bí Kristi ti fẹ́ràn ìjọ, tí ó sì fi ara rẹ̀ fún un.

26 Ó ṣe èyí láti yà á sọ́tọ̀. Ó sọ ọ́ di mímọ́ lẹ́yìn tí ó ti fi omi wẹ̀ ẹ́ nípa ọ̀rọ̀ iwaasu.

27 Kí ó lè mú ìjọ wá sọ́dọ̀ ara rẹ̀ bí ìjọ tí ó lọ́lá, tí kò ní àléébù kankan, tabi kí ó hunjọ, tabi kí ó ní nǹkan àbùkù kankan, ṣugbọn kí ó lè jẹ́ ìjọ mímọ́ tí kò ní èérí.

28 Bẹ́ẹ̀ ni ó yẹ kí àwọn ọkọ fẹ́ràn àwọn aya wọn, bí wọ́n ti fẹ́ràn ara tiwọn. Ẹni tí ó bá fẹ́ràn aya rẹ̀, òun tìkararẹ̀ ni ó fẹ́ràn.

29 Nítorí kò sí ẹnìkan tí ó kórìíra ara rẹ̀. Ńṣe ni eniyan máa ń tọ́jú ara rẹ̀, tí ó sì máa ń kẹ́ ẹ. Bẹ́ẹ̀ ni Kristi ń ṣe sí ìjọ.

30 Nítorí ẹ̀yà ara Kristi ni a jẹ́.

31 Gẹ́gẹ́ bí Ìwé Mímọ́ ti sọ, pé, “Nítorí náà ni ọkunrin yóo ṣe fi baba ati ìyá rẹ̀ sílẹ̀, tí yóo darapọ̀ pẹlu aya rẹ̀, àwọn mejeeji yóo wá di ara kan.”

32 Àṣírí ńlá ni èyí. Mò ń sọ nípa ipò tí Kristi wà sí ìjọ.

33 Àkàwé yìí ba yín mu. Ẹnìkọ̀ọ̀kan yín níláti fẹ́ràn aya rẹ̀ bí òun tìkararẹ̀. Aya sì níláti bọ̀wọ̀ fún ọkọ rẹ̀.

orí

1 2 3 4 5 6