Efesu 6 BM

Ọmọ ati Òbí

1 Ẹ̀yin ọmọ, ẹ máa gbọ́ ti àwọn òbí yín nítorí pé bẹ́ẹ̀ ni ó dára.

2 “Bọ̀wọ̀ fún baba ati ìyá rẹ.” Èyí níí ṣe òfin kinni pẹlu ìlérí, pé

3 “Kí ó lè dára fún ọ, ati kí o lè pẹ́ lórí ilẹ̀ náà.”

4 Ẹ̀yin òbí, ẹ má ṣe mú àwọn ọmọ yín bínú. Títọ́ ni kí ẹ máa tọ́ wọn ninu ẹ̀kọ́ ati ìlànà ti onigbagbọ.

Ẹrú ati Ọ̀gá

5 Ẹ̀yin ẹrú, ẹ máa gbọ́ ti àwọn tí wọ́n jẹ́ oluwa yín nípa ti ara, pẹlu ọ̀wọ̀ ati ìbẹ̀rù, pẹlu ọkàn kan gẹ́gẹ́ bí ẹni pé Kristi ni ẹ̀ ń ṣe é fún.

6 Kí ó má ṣe jẹ́ pé nígbà tí wọ́n bá ń ṣọ́ yín nìkan ni ẹ óo máa ṣiṣẹ́ bí ìgbà tí ẹ fẹ́ gba ìyìn eniyan. Ṣugbọn bí ẹrú Kristi, ẹ máa ṣe ìfẹ́ Ọlọrun láti ọkàn wá.

7 Ẹ máa ṣe iṣẹ́ yín pẹlu inú dídùn, bí ẹni pé fún Oluwa, kì í ṣe fún eniyan.

8 Nítorí ẹ mọ̀ pé ohun rere tí ẹnìkọ̀ọ̀kan yín bá ṣe, olúwarẹ̀ ìbáà jẹ́ ẹrú tabi kí ó jẹ́ òmìnira, yóo rí èrè gbà lọ́dọ̀ Oluwa.

9 Ẹ̀yin ọ̀gá, bákan náà ni kí ẹ máa ṣe sí àwọn ẹrú yín. Ẹ má máa dẹ́rù bà wọ́n. Ẹ ranti pé ati àwọn, ati ẹ̀yin, ẹ ní Oluwa kan lọ́run, tí kì í ṣe ojuṣaaju.

Ìjàkadì pẹlu Ibi

10 Ní ìparí, ẹ jẹ́ alágbára ninu Oluwa, kí ẹ fi agbára rẹ̀ ṣe okun yín.

11 Ẹ gbé gbogbo ihamọra Ọlọrun wọ̀, kí ẹ lè dúró láti dojú kọ èṣù pẹlu ọgbọ́n àrékérekè rẹ̀.

12 Nítorí kì í ṣe eniyan ni à ń bá jagun, bíkòṣe àwọn ẹ̀mí burúkú ojú ọ̀run, àwọn aláṣẹ ati àwọn alágbára òkùnkùn ayé yìí.

13 Nítorí èyí, ẹ gbé gbogbo ihamọra Ọlọrun wọ̀, kí ẹ lè dìde dúró láti jà nígbà tí ọjọ́ ibi bá dé. Nígbà tí ìjà bá sì dópin, kí ẹ lè wà ní ìdúró.

14 Nítorí náà, ẹ dúró gbọningbọnin. Ẹ fi òtítọ́ ṣe ọ̀já ìgbànú yín. Ẹ fi òdodo bo àyà yín bí apata.

15 Ẹ jẹ́ kí ìmúrasílẹ̀ láti waasu ìyìn rere alaafia jẹ́ bàtà ẹsẹ̀ yín.

16 Lẹ́yìn gbogbo nǹkan wọnyi, ẹ fi igbagbọ ṣe ààbò yín. Nípa rẹ̀ ni ẹ óo lè fi pa iná gbogbo ọfà amúbíiná tí èṣù ń ta.

17 Ẹ fi ìgbàlà ṣe fìlà onírin tí ẹ óo máa dé, kí ẹ sì mú idà Ẹ̀mí Mímọ́, tíí ṣe ọ̀rọ̀ Ọlọrun.

18 Ẹ máa gbadura nígbà gbogbo, kí ẹ máa fi gbogbo ẹ̀bẹ̀ yín siwaju Ọlọrun nípa agbára Ẹ̀mí Mímọ́. Nítorí náà, ẹ máa gbadura láì sùn, láì wo, fún gbogbo àwọn eniyan Ọlọrun.

19 Ẹ máa gbadura fún èmi gan-an alára, pé kí n lè mọ ohun tí ó yẹ kí n sọ nígbà tí n óo bá sọ̀rọ̀. Ati pé kí n lè fi ìgboyà sọ̀rọ̀ tí àwọn eniyan yóo fi mọ àṣírí ìyìn rere

20 tí mo jẹ́ ikọ̀ fún, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n fi ẹ̀wọ̀n dè mí. Ẹ gbadura pé kí n lè fi ìgboyà sọ̀rọ̀ bí ó ti yẹ.

Gbolohun Ìparí

21 Kí ẹ lè mọ bí nǹkan ti ń lọ sí lọ́dọ̀ mi, ati ohun tí mò ń ṣe, Tukikọsi yóo sọ gbogbo rẹ̀ fun yín. Àyànfẹ́ arakunrin ni, ati iranṣẹ tí ó ṣe é gbẹ́kẹ̀lé ninu iṣẹ́ Oluwa.

22 Ìdí tí mo fi rán an si yín ni pé kí ẹ lè mọ bí gbogbo nǹkan ti ń lọ sí lọ́dọ̀ wa, kí ọkàn yín lè balẹ̀.

23 Kí alaafia ati ìfẹ́ pẹlu igbagbọ láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun Baba ati Oluwa Jesu Kristi, kí ó wà pẹlu àwọn onigbagbọ.

24 Kí oore-ọ̀fẹ́ wà pẹlu gbogbo àwọn tí ó fẹ́ràn Oluwa wa, Jesu Kristi pẹlu ìfẹ́ tí kò lópin.

orí

1 2 3 4 5 6