9 Ati pé kí n ṣe àlàyé nípa ètò àṣírí yìí, tí Ọlọrun ẹlẹ́dàá ohun gbogbo ti fi pamọ́ láti ìgbà àtijọ́,
10 kí ó lè sọ ọ́ di mímọ̀ ní àkókò yìí láti ọ̀dọ̀ ìjọ, kí ó sì lè fihan àwọn alágbára ati àwọn aláṣẹ tí ó wà ninu àwọn ọ̀run bí ọgbọ́n Ọlọrun ti pọ̀ tó ní oríṣìíríṣìí ọ̀nà.
11 Ọlọrun ṣe èyí gẹ́gẹ́ bí ètò rẹ̀, láti ayérayé, tí ó mú ṣẹ ninu Kristi Jesu Oluwa wa.
12 Nípasẹ̀ rẹ̀ ni a fi ní ìgboyà láti dé ọ̀dọ̀ Ọlọrun. A sì ní ìdánilójú pé a ti rí ààyè dé ọ̀dọ̀ rẹ̀ nípa igbagbọ.
13 Nítorí èyí, mò ń gbadura pé kí ọkàn yín má ṣe rẹ̀wẹ̀sì nítorí ìpọ́njú tí mò ń rí nítorí yín. Ohun ìṣògo ni èyí jẹ́ fun yín.
14 Nítorí èyí ni mo ṣe ń fi ìkúnlẹ̀ gbadura sí Baba,
15 tí à ń fi orúkọ rẹ̀ pe gbogbo ìdílé lọ́run ati láyé.