24 Nígbà náà ni Anasi fi Jesu ranṣẹ ní dídè sí Kayafa, Olórí Alufaa.
25 Simoni Peteru wà níbi tí ó dúró, tí ó ń yáná. Wọ́n sọ fún un pé, “Ṣé kì í ṣe pé ọ̀kan ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ni ọ́?”Ó sẹ́, ó ní, “Rárá o!”
26 Ọ̀kan ninu àwọn ẹrú Olórí Alufaa, tí ó jẹ́ ẹbí ẹni tí Peteru gé létí bi Peteru pé, “Ǹjẹ́ n kò rí ọ ninu ọgbà pẹlu rẹ̀?”
27 Peteru tún sẹ́. Lẹsẹkẹsẹ àkùkọ kan bá kọ.
28 Lẹ́yìn náà wọ́n mú Jesu kúrò níwájú Kayafa lọ sí ààfin. Ilẹ̀ ti mọ́ ní àkókò yìí. Àwọn fúnra wọn kò wọ inú ààfin, kí wọn má baà di aláìmọ́, kí wọn baà lè jẹ àsè Ìrékọjá.
29 Pilatu bá jáde lọ sọ́dọ̀ wọn lóde, ó bi wọ́n pé, “Ẹ̀sùn wo ni ẹ fi kan ọkunrin yìí?”
30 Wọ́n dá a lóhùn pé, “Bí ọkunrin yìí kò bá ṣe nǹkan burúkú ni, a kì bá tí fà á lé ọ lọ́wọ́ fún ìdájọ́.”