34 Jesu dáhùn pé, “O wí èyí fúnrarẹ ni àbí ẹlòmíràn ni ó sọ bẹ́ẹ̀ fún ọ nípa mi?”
35 Pilatu dáhùn pé, “Èmi í ṣe Juu bí? Àwọn eniyan rẹ ati àwọn olórí alufaa ni wọ́n fà ọ́ wá sọ́dọ̀ mi. Kí ni o ṣe?”
36 Jesu dá a lóhùn pé, “Ìjọba mi kì í ṣe ti ayé yìí. Bí ó bá jẹ́ pé ti ayé yìí ni ìjọba mi, àwọn iranṣẹ mi ìbá jà; àwọn Juu kì bá tí lè mú mi. Ṣùgbọ́n ìjọba mi kì í ṣe ti ìhín.”
37 Pilatu wá bi í pé, “Èyí ni pé ọba ni ọ́?”Jesu dá a lóhùn pé, “O ti fi ẹnu ara rẹ wí pé Ọba ni mí. Nítorí rẹ̀ ni a ṣe bí mi, nítorí bẹ́ẹ̀ ni mo ṣe wá sáyé, kí n lè jẹ́rìí sí òtítọ́. Gbogbo ẹni tí ó bá ń ṣe ti òtítọ́ yóo gbọ́ ohùn mi.”
38 Pilatu bi í pé, “Kí ni òtítọ́?”Nígbà tí ó ti sọ báyìí tán, ó tún jáde lọ sọ́dọ̀ àwọn Juu, ó sọ fún wọn pé, “Èmi kò rí ẹ̀bi kankan tí ó jẹ.
39 Ṣugbọn ẹ ní àṣà kan, pé kí n dá ẹnìkan sílẹ̀ fun yín ní àkókò Àjọ̀dún Ìrékọjá. Ṣé ẹ fẹ́ kí n dá ‘Ọba àwọn Juu’ sílẹ̀ fun yín?”
40 Wọ́n tún kígbe pé, “Òun kọ́! Baraba ni kí o dá sílẹ̀!” (Ọlọ́ṣà paraku ni Baraba yìí.)