2 Àwọn ọmọ-ogun bá fi ìtàkùn ẹlẹ́gùn-ún hun adé, wọ́n fi dé e lórí; wọn wọ̀ ọ́ ní ẹ̀wù kan bíi ẹ̀wù àlàárì,
3 wọ́n wá ń lọ sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n ń kí i pé, “Kabiyesi! Ọba àwọn Juu!” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń gbá a létí.
4 Pilatu tún jáde lọ sóde, ó sọ fún àwọn Juu pé, “Mò ń mú un tọ̀ yín bọ̀ wá sóde, kí ẹ lè mọ̀ pé èmi kò rí i pé ó jẹ̀bi ohunkohun.”
5 Nígbà náà ni Jesu jáde pẹlu adé ẹ̀gún ati ẹ̀wù àlàárì. Pilatu wá sọ fún wọn pé, “Ẹ wò ó, ọkunrin náà nìyí.”
6 Nígbà tí àwọn olórí alufaa ati àwọn ẹ̀ṣọ́ rí i, wọ́n kígbe pé, “Kàn án mọ́ agbelebu!”Pilatu sọ fún wọn pé, “Ẹ̀yin fúnra yín ẹ mú un, kí ẹ kàn án mọ́ agbelebu, nítorí ní tèmi, n kò rí ẹ̀bi kankan tí ó jẹ.”
7 Àwọn Juu dá a lóhùn pé, “A ní òfin kan, nípa òfin náà, ikú ni ó tọ́ sí i, nítorí ó fi ara rẹ̀ ṣe Ọmọ Ọlọrun.”
8 Nígbà tí Pilatu gbọ́ gbolohun yìí, ẹ̀rù túbọ̀ bà á.