32 Àwọn ọmọ-ogun bá lọ, wọ́n dá ekinni-keji àwọn tí wọ́n kàn mọ́ agbelebu pẹlu Jesu lójúgun.
33 Ṣugbọn nígbà tí wọ́n dé ọ̀dọ̀ Jesu wọ́n rí i pé ó ti kú, nítorí náà wọn kò dá a lójúgun.
34 Ṣugbọn ọmọ-ogun kan fi ọ̀kọ̀ gún un lẹ́gbẹ̀ẹ́, ẹ̀jẹ̀ ati omi bá tú jáde.
35 (Ẹni tí ọ̀rọ̀ yìí ṣe ojú rẹ̀ ni ó jẹ́rìí, òtítọ́ ni ẹ̀rí rẹ̀, ó mọ̀ pé òtítọ́ ni òun sọ, kí ẹ̀yin lè gbàgbọ́.)
36 Gbogbo èyí rí bẹ́ẹ̀ kí Ìwé Mímọ́ lè ṣẹ tí ó wí pé, “Kò sí egungun rẹ̀ kan tí wọ́n ṣẹ́.”
37 Ìwé Mímọ́ tún wí níbòmíràn pé, “Wọn yóo wo ẹni tí wọ́n fi ọ̀kọ̀ gún.”
38 Lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ wọnyi, Josẹfu ará Arimatia bẹ Pilatu pé kí ó jẹ́ kí òun gbé òkú Jesu lọ. Josẹfu yìí jẹ́ ọmọ-ẹ̀yìn Jesu tí ó fara pamọ́ nítorí ó bẹ̀rù àwọn Juu. Pilatu bá fún un ní àṣẹ láti gbé òkú Jesu. Ó bá lọ gbé e.