41 Àwọn mìíràn ń sọ pé, “Òun ni Mesaya.”Ṣugbọn àwọn mìíràn ń sọ pé, “Báwo ni Mesaya ti ṣe lè wá láti Galili?
42 Ṣebí Ìwé Mímọ́ ti sọ pé láti inú ìdílé Dafidi, ní Bẹtilẹhẹmu ìlú Dafidi, ni Mesaya yóo ti wá?”
43 Ni ìyapa bá bẹ́ sáàrin àwọn eniyan nítorí rẹ̀.
44 Àwọn kan ninu wọn fẹ́ mú un, ṣugbọn kò sí ẹni tí ó fi ọwọ́ kàn án.
45 Nígbà tí àwọn ẹ̀ṣọ́ Tẹmpili tí wọ́n rán lọ mú Jesu pada dé ọ̀dọ̀ àwọn olórí alufaa ati àwọn Farisi, wọ́n bi wọ́n pé, “Kí ló dé tí ẹ kò fi mú un wá?”
46 Àwọn ẹ̀ṣọ́ ọ̀hún bá dáhùn pé, “Ẹnikẹ́ni kò sọ̀rọ̀ bí ọkunrin yìí rí!”
47 Àwọn Farisi bá bi wọ́n pé, “Àbí ẹ̀yin náà ti di ara àwọn tí ó ń tàn jẹ?