10 Wọ́n bi í pé, “Báwo ni ojú rẹ́ ti ṣe là?”
11 Ó dá wọn lóhùn pé, “Ọkunrin tí wọn ń pè ní Jesu ni ó po amọ̀, tí ó fi lẹ̀ mí lójú, tí ó sọ fún mi pé kí n lọ bọ́jú ní adágún Siloamu. Mo lọ, mo bọ́jú, mo sì ríran.”
12 Wọ́n bi í pé, “Níbo ni ọkunrin náà wà?”Ó dáhùn pé, “Èmi kò mọ̀.”
13 Àwọn kan bá mú ọkunrin tí ojú rẹ̀ ti fọ́ rí yìí lọ sọ́dọ̀ àwọn Farisi.
14 (Ọjọ́ Ìsinmi ni ọjọ́ tí Jesu po amọ̀, tí ó fi la ojú ọkunrin náà.)
15 Àwọn Farisi tún bi ọkunrin náà bí ó ti ṣe ríran. Ó sọ fún wọn pé, “Ó lẹ amọ̀ mọ́ mi lójú, mo lọ bọ́jú, mo bá ríran.”
16 Àwọn kan ninu àwọn Farisi ń sọ pé, “Ọkunrin yìí kò ti ọ̀dọ̀ Ọlọrun wá, nítorí kò pa òfin Ọjọ́ Ìsinmi mọ́.”Ṣugbọn àwọn mìíràn ń sọ pé “Báwo ni ẹni tí ó jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀ ṣe lè ṣe irú iṣẹ́ ìyanu yìí?” Ìyapa bá bẹ́ sáàrin wọn.