9 Nítorí náà, láti ọjọ́ tí a ti gbọ́ ìròyìn yín, àwa náà kò sinmi láti máa gbadura fun yín. À ń bẹ̀bẹ̀ pé kí Ọlọrun lè jẹ́ kí ẹ mọ ìfẹ́ rẹ̀ lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ pẹlu gbogbo ọgbọ́n, kí ó sì fun yín ní òye nípa nǹkan ti ẹ̀mí.
10 A tún ń gbadura pé kí ìgbé-ayé yín lè jẹ́ èyí tí ó wu Oluwa lọ́nà gbogbo, kí iṣẹ́ rere yín máa pọ̀ sí i, kí ẹ máa tẹ̀síwájú ninu ìmọ̀ Ọlọrun.
11-12 Ati pé kí Ọlọrun fun yín ní agbára gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ ògo rẹ̀, kí ó fun yín ní ìfaradà ninu ohun gbogbo, pẹlu sùúrù ati ayọ̀. Kí ẹ máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Baba wa tí ó kà yín yẹ láti ní ìpín ninu ogún àwọn eniyan Ọlọrun ninu ìmọ́lẹ̀.
13 Baba wa náà ni ó gbà wá lọ́wọ́ agbára òkùnkùn, ó sì mú wa wá sinu ìjọba àyànfẹ́ Ọmọ rẹ̀.
14 Nípasẹ̀ ọmọ rẹ̀ yìí ni a fi ní ìdáǹdè, àní ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ wa.
15 Eniyan kò lè rí Ọlọrun, ṣugbọn ọmọ yìí ni àwòrán rẹ̀, òun ni àkọ́bí ohun gbogbo tí a dá.
16 Nítorí pé, nípasẹ̀ rẹ̀ ni a ti dá ohun gbogbo, lọ́run ati láyé: ati ohun tí a rí, ati ohun tí a kò rí, ìbáà ṣe ìtẹ́ ọba, tabi ìjọba, tabi àwọn alágbára, tabi àwọn aláṣẹ. Nípasẹ̀ rẹ̀ ni a ti dá gbogbo nǹkan, nítorí tirẹ̀ ni a sì ṣe dá wọn.