1 Ẹ̀yin ará, à ń bẹ̀ yín nípa ọ̀rọ̀ lórí ìgbà tí Oluwa yóo farahàn ati ìgbà tí yóo kó wa jọ sọ́dọ̀ ara rẹ̀,
2 ẹ má jẹ́ kí ọkàn yín tètè mì, tabi kí èrò yín dàrú lórí ọ̀rọ̀ pé Ọjọ́ Oluwa ti dé. Kì báà jẹ́ pé ninu ọ̀rọ̀ wa tabi ninu Ẹ̀mí ni wọ́n ti rò pé a sọ ọ́, tabi bóyá ninu àlàyékálàyé kan tabi ìwé kan tí wọ́n rò pé ọ̀dọ̀ wa ni ó ti wá.
3 Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni tàn yín jẹ lọ́nàkọnà nípa ọ̀rọ̀ yìí. Nítorí kí ọjọ́ Oluwa tó dé, ọ̀tẹ̀ nípa ti ẹ̀sìn níláti kọ́kọ́ ṣẹlẹ̀, kí Ẹni Ibi nnì, ẹni ègbé nnì sì farahàn.
4 Yóo lòdì sí ohun gbogbo tí ó jẹ́ ti Ọlọrun tabi tí ó jẹ mọ́ ti ẹ̀sìn. Yóo gbé ara rẹ̀ ga ju èyíkéyìí ninu àwọn oriṣa lọ; yóo tilẹ̀ lọ jókòó ninu Tẹmpili Ọlọrun, yóo sì fi ara hàn pé òun ni Ọlọrun.
5 Ẹ ranti pé a ti sọ gbogbo èyí fun yín nígbà tí a wà lọ́dọ̀ yín.
6 Ǹjẹ́ nisinsinyii, ẹ mọ ohun tí ó ń ká a lọ́wọ́ kò, tí kò jẹ́ kí ó farahàn títí àkókò rẹ̀ yóo fi tó.