Tẹsalonika Keji 1 BM

Ìkíni

1 Èmi Paulu, ati Silifanu, ati Timoti, ni à ń kọ ìwé yìí sí ìjọ Tẹsalonika, tíí ṣe ìjọ Ọlọrun Baba ati ti Jesu Kristi Oluwa.

2 Kí oore-ọ̀fẹ́ ati alaafia láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun Baba ati Oluwa Jesu Kristi máa wà pẹlu yín.

Ìdájọ́ Nígbà Tí Jesu Bá Dé

3 Ẹ̀yin ará, ó yẹ kí á máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun nígbà gbogbo nítorí yín. Ó tọ́ bẹ́ẹ̀ nítorí pé igbagbọ yín ń tóbi sí i, ìfẹ́ ẹnìkọ̀ọ̀kan yín sí ara yín sì ń pọ̀ sí i.

4 Àwa fúnra wa ń fọ́nnu nípa yín láàrin àwọn ìjọ Ọlọrun. À ń ròyìn ìfaradà ati igbagbọ yín ninu gbogbo inúnibíni ati ìpọ́njú tí ẹ̀ ń faradà.

5 Ìfaradà yín jẹ́ ẹ̀rí ìdájọ́ òdodo Ọlọrun láti kà yín yẹ fún ìjọba rẹ̀ tí ẹ̀ ń tìtorí rẹ̀ jìyà.

6 Nítorí ó tọ́ lójú Ọlọrun láti fi ìpọ́njú san ẹ̀san fún àwọn tí wọn ń pọn yín lójú,

7 ati láti fún ẹ̀yin tí wọn ń pọ́n lójú, ati àwa náà ní ìsinmi, nígbà tí Oluwa wa, Jesu, bá farahàn láti ọ̀run ninu ọwọ́ iná pẹlu àwọn angẹli tí wọ́n jẹ́ alágbára.

8 Nígbà náà ni yóo gbẹ̀san lára àwọn tí kò mọ Ọlọrun ati àwọn tí kò gba ọ̀rọ̀ ìyìn rere Oluwa wa Jesu.

9 Àwọn yìí ni wọn yóo gba ìdálẹ́bi sí ìparun ayérayé, wọn yóo sì kúrò níwájú Oluwa ati ògo agbára rẹ̀;

10 nígbà tí Oluwa bá dé ní ọjọ́ náà láti gba ògo lọ́dọ̀ àwọn ẹni mímọ́ rẹ̀, nígbà tí gbogbo àwọn tí ó gbàgbọ́ yóo máa yẹ́ ẹ sí, nítorí wọ́n gba ẹ̀rí tí a jẹ́ fún wọn gbọ́.

11 Nítorí èyí ni a fi ń gbadura fun yín nígbà gbogbo, pé kí Ọlọrun wa lè kà yín yẹ fún ìpè tí ó pè yín, kí ó mú èrò gbogbo ṣẹ, kí ó sì fi agbára fun yín láti máa gbé ìgbé-ayé tí ó yẹ onigbagbọ;

12 kí ẹ lè yin orúkọ Oluwa wa Jesu lógo, kí òun náà sì yìn yín, gẹ́gẹ́ bí oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun wa ati ti Oluwa Jesu Kristi.

orí

1 2 3