1 Ẹ̀yin ará, kò nílò pé a tún ń kọ̀wé si yín mọ́ nípa ti àkókò ati ìgbà tí Oluwa yóo farahàn.
2 Nítorí ẹ̀yin fúnra yín ti mọ̀ dájú pé bí ìgbà tí olè bá dé lóru ni ọjọ́ tí Oluwa yóo dé yóo rí.
3 Nígbà tí àwọn eniyan bá ń wí pé, “Àkókò alaafia ati ìrọ̀ra nìyí,” nígbà náà ni ìparun yóo dé bá wọn lójijì, wọn kò sì ní ríbi sá sí; yóo dàbí ìgbà tí obinrin bá lóyún, tí kò mọ ìgbà tí òun yóo bí.
4 Ẹ̀yin ará, ẹ̀yin kò sí ninu òkùnkùn ní tiyín, tí ọjọ́ náà yóo fi dé ba yín bí ìgbà tí olè bá dé.
5 Nítorí ọmọ ìmọ́lẹ̀ ni gbogbo yín; ọmọ tí a bí ní àkókò tí ojú ti là sí òtítọ́, ẹ kì í ṣe àwọn tí a bí ní àkókò àìmọ̀kan; ẹ kì í ṣe ọmọ òkùnkùn.
6 Nítorí náà, ẹ má ṣe jẹ́ kí á máa sùn bí àwọn yòókù, ṣugbọn ẹ jẹ́ kí á máa ṣọ́nà, kí á sì máa ṣọ́ra.
7 Nítorí òru ni àwọn tí ń sùn ń sùn, òru sì ni àwọn tí ó ń mutí ń mutí.
8 Ṣugbọn ní tiwa, ojúmọmọ ni iṣẹ́ tiwa, nítorí náà, ẹ jẹ́ kí á farabalẹ̀, kí á wọ aṣọ ìgbàyà igbagbọ ati ìfẹ́, kí á dé fìlà ìrètí ìgbàlà.
9 Nítorí Ọlọrun kò pè wá sinu ibinu, ṣugbọn sí inú ìgbàlà nípasẹ̀ Oluwa wa Jesu Kristi,
10 tí ó kú nítorí tiwa, ni ó pè wá sí, pé bí à ń ṣọ́nà ni, tabi a sùn ni, kí á jọ wà láàyè pẹlu rẹ̀.
11 Nítorí náà, ẹ máa tu ara yín ninu, kí ẹ sì máa fún ara yín ní ìwúrí, bí ẹ ti ń ṣe.
12 Ẹ̀yin ará, à ń bẹ̀ yín pé kí ẹ máa bu ọlá fún àwọn tí ń ṣe làálàá láàrin yín, tí wọn ń darí yín nípa ti Oluwa, tí wọn ń gbà yín níyànjú.
13 Ẹ máa fi ìfẹ́ yẹ́ wọn sí gidigidi nítorí iṣẹ́ wọn. Ẹ máa wà ní alaafia láàrin ara yín.
14 Ará, à ń rọ̀ yín pé kí ẹ máa gba àwọn tí ń ṣe ìmẹ́lẹ́ níyànjú; bẹ́ẹ̀ náà ni kí ẹ máa ṣe sí àwọn tí ó ní ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn; ẹ máa ran àwọn aláìlera lọ́wọ́; ẹ máa mú sùúrù pẹlu gbogbo eniyan.
15 Kí ẹ rí i pé ẹnikẹ́ni kò fi burúkú gbẹ̀san burúkú lára ẹnikẹ́ni. Ṣugbọn nígbà gbogbo kí ẹ máa lépa nǹkan rere láàrin ara yín ati láàrin gbogbo eniyan.
16 Ẹ máa yọ̀ nígbà gbogbo.
17 Ẹ máa gbadura láì sinmi.
18 Ẹ máa dúpẹ́ ninu ohun gbogbo nítorí èyí ni ìfẹ́ Ọlọrun nípa Kristi Jesu fun yín.
19 Ẹ má máa da omi tútù sí àwọn tí ó ní ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́ lọ́kàn.
20 Ẹ má máa fi ojú tẹmbẹlu ẹ̀bùn wolii.
21 Ẹ máa wádìí ohun gbogbo dájú, kí ẹ sì di èyí tí ó bá dára mú ṣinṣin.
22 Ẹ máa takété sí ohunkohun tí ó bá burú.
23 Kí Ọlọrun alaafia kí ó yà yín sí mímọ́ patapata; kí ó pa gbogbo ẹ̀mí yín mọ́ ati ọkàn, ati ara yín. Kí èyíkéyìí má ní àbùkù nígbà tí Oluwa wa Jesu Kristi bá farahàn.
24 Ẹni tí ó pè yín yóo ṣe bẹ́ẹ̀, nítorí pé olóòótọ́ ni.
25 Ẹ̀yin ará, ẹ máa gbadura fún wa.
26 Ẹ fi ìfẹnukonu mímọ́ kí gbogbo àwọn onigbagbọ.
27 Mo fi Oluwa bẹ̀ yín, ẹ ka ìwé yìí fún gbogbo ìjọ.
28 Kí oore-ọ̀fẹ́ Oluwa wa Jesu Kristi kí ó wà pẹlu yín.