Tẹsalonika Kinni 1 BM

Ìkíni

1 Èmi Paulu, ati Silifanu, ati Timoti, ni à ń kọ ìwé yìí sí ìjọ Tẹsalonika, tíí ṣe ìjọ Ọlọrun Baba ati ti Jesu Kristi Oluwa.Kí oore-ọ̀fẹ́ ati alaafia máa wà pẹlu yín.

Ìdúpẹ́

2 À ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun nígbà gbogbo nítorí gbogbo yín, a sì ń ranti yín ninu adura wa nígbà gbogbo.

3 Ninu adura wa sí Ọlọrun Baba wa, à ń ranti bí igbagbọ yín ti ń mú kí ẹ ṣiṣẹ́, tí ìfẹ́ yín ń jẹ́ kí ẹ ṣe akitiyan, tí ìrètí tí ẹ ní ninu Oluwa wa Jesu Kristi sì ń mú kí ẹ ní ìfaradà.

4 Ẹ̀yin ará, àyànfẹ́ Ọlọrun, a mọ̀ pé Ọlọrun ni ó yàn yín.

5 Nígbà tí a mú ìyìn rere wá sí ọ̀dọ̀ yín, a kò mú un wá pẹlu ọ̀rọ̀ ẹnu nìkan; ṣugbọn pẹlu agbára ninu Ẹ̀mí Mímọ́ ni, ati pẹlu ọpọlọpọ ẹ̀rí tí ó dáni lójú. Ẹ̀yin náà kúkú ti mọ irú ẹni tí a jẹ́ nítorí tiyín nígbà tí a wà láàrin yín.

6 Ẹ̀yin náà wá ń fara wé wa, ẹ sì ń fara wé Oluwa. Láàrin ọpọlọpọ inúnibíni ẹ gba ọ̀rọ̀ ìyìn rere tayọ̀tayọ̀ láti ọ̀dọ̀ Ẹ̀mí Mímọ́.

7 Ẹ wá di àpẹẹrẹ fún gbogbo àwọn onigbagbọ tí ó wà ní Masedonia ati Akaya.

8 Nítorí ẹ̀yin ni ẹ tan ìyìn rere ọ̀rọ̀ Oluwa káàkiri, kì í ṣe ní Masedonia ati Akaya nìkan, ṣugbọn níbi gbogbo ni ìròyìn igbagbọ yín sí Ọlọrun ti tàn dé. Kò ṣẹ̀ṣẹ̀ tún ní pé à ń sọ ohunkohun mọ́.

9 Nítorí wọ́n ń sọ bí ẹ ti ṣe gbà wá nígbà tí a dé ọ̀dọ̀ yín, ati bí ẹ ti ṣe yipada kúrò ninu ìbọ̀rìṣà, láti máa sin Ọlọrun tòótọ́ tíí ṣe Ọlọrun alààyè;

10 ati bí ẹ ti ń retí Jesu, Ọmọ rẹ̀, láti ọ̀run wá, ẹni tí a jí dìde ninu òkú, tí ó yọ wá kúrò ninu ibinu tí ń bọ̀.

orí

1 2 3 4 5