Tẹsalonika Kinni 3 BM

1 Nítorí náà, nígbà tí ara wa kò gbà á mọ́, a pinnu pé kí ó kúkú ku àwa nìkan ní Atẹni;

2 ni a bá rán Timoti si yín, ẹni tí ó jẹ́ arakunrin wa ati alábàáṣiṣẹ́pọ̀ pẹlu Ọlọrun ninu iṣẹ́ ìyìn rere ti Kristi, kí ó lè máa gbà yín níyànjú, kí igbagbọ yín lè dúró gbọnin-gbọnin.

3 Kí ẹnikẹ́ni má baà tàn yín jẹ ní àkókò inúnibíni yìí. Nítorí ẹ̀yin fúnra yín mọ̀ pé onigbagbọ níláti rí irú ìrírí yìí.

4 Nítorí nígbà tí a wà lọ́dọ̀ yín, a ti sọ fun yín tẹ́lẹ̀ pé a níláti jìyà. Bẹ́ẹ̀ ni ó sì rí, bí ẹ̀yin náà ti mọ̀.

5 Nítorí náà, èmi náà kò lè fi ara dà á mọ́, ni mo bá ranṣẹ láti wá wádìí nípa ìdúró yín, kí ó má baà jẹ́ pé olùdánwò ti dán yín wò, kí akitiyan wa má baà já sí òfo.

6 Ṣugbọn nisinsinyii, Timoti ti ti ọ̀dọ̀ yín dé, ó ti fún wa ní ìròyìn rere nípa igbagbọ ati ìfẹ́ yín. Ó ní ẹ̀ ń ranti wa sí rere nígbà gbogbo, ati pé bí ọkàn yin ti ń fà wá, bẹ́ẹ̀ ni ọkàn ti àwa náà ń fà yín.

7 Ará, ìròyìn yìí fún wa ní ìwúrí nípa yín, nítorí igbagbọ yín, a lè gba gbogbo ìṣòro ati inúnibíni tí à ń rí.

8 Nítorí pé bí ẹ bá dúró gbọningbọnin ninu Oluwa nisinsinyii, a jẹ́ pé wíwà láàyè wa kò jẹ́ lásán.

9 Nítorí pé ọpẹ́ mélòó ni a lè dá lọ́wọ́ Ọlọrun nítorí yín, lórí gbogbo ayọ̀ tí à ń yọ̀ nítorí yín níwájú Ọlọrun wa?

10 À ń gbadura kíkankíkan tọ̀sán-tòru pé kí á lè fi ojú kàn yín, kí á lè ṣe àtúnṣe níbi tí igbagbọ yín bá kù kí ó tó.

11 Ǹjẹ́ nisinsinyii, kí Ọlọrun Baba wa fúnrarẹ̀ ati Oluwa wa Jesu kí ó tọ́ ẹsẹ̀ wa sí ọ̀nà dé ọ̀dọ̀ yín.

12 Kí Oluwa mú kí ìfẹ́ yín sí ara yín ati sí gbogbo eniyan kí ó pọ̀ sí i, kí ó sì túbọ̀ jinlẹ̀, gẹ́gẹ́ bí tiwa ti rí si yín.

13 Kí Oluwa fi agbára fun yín, kí ọkàn yín lè wà ní ipò mímọ́, láìní àléébù, níwájú Ọlọrun Baba wa nígbà tí Oluwa wa Jesu bá farahàn pẹlu gbogbo àwọn ẹni mímọ́ rẹ̀.

orí

1 2 3 4 5