6 Ẹ̀yin ará, à ń pàṣẹ fun yín ní orúkọ Oluwa wa Jesu Kristi pé kí ẹ yẹra fún àwọn onigbagbọ tí wọn bá ń rìn ségesège, tí wọn kò tẹ̀lé ẹ̀kọ́ tí ẹ ti kọ́ lọ́dọ̀ wa.
7 Nítorí ẹ̀yin fúnra yín mọ bí ó ti yẹ kí ẹ ṣe àfarawé wa, nítorí a kò rìn ségesège nígbà tí a wà láàrin yín.
8 Bẹ́ẹ̀ ni a kò jẹ oúnjẹ ẹnikẹ́ni ninu yín lọ́fẹ̀ẹ́. Ṣugbọn ninu làálàá ati ìṣòro ni à ń ṣiṣẹ́ tọ̀sán-tòru, kí á má baà ni ẹnikẹ́ni ninu yín lára.
9 Kì í ṣe pé a kò ní ẹ̀tọ́ láti jẹun lọ́dọ̀ yín; ṣugbọn a kò ṣe bẹ́ẹ̀ kí á lè fi ara wa ṣe àpẹẹrẹ fun yín, kí ẹ lè fara wé wa.
10 Nítorí nígbà tí a wà lọ́dọ̀ yín, a pàṣẹ fun yín pé bí ẹnikẹ́ni bá kọ̀ tí kò ṣiṣẹ́, ẹ má jẹ́ kí ó jẹun.
11 Nítorí a gbọ́ pé àwọn kan ninu yín ń rìn ségesège, wọn kì í ṣiṣẹ́ rárá, ẹsẹ̀ ni wọ́n fi í máa wọ́lẹ̀ kiri.
12 A pàṣẹ fún irú àwọn bẹ́ẹ̀, a tún ń rọ̀ wọ́n ninu Oluwa Jesu Kristi pé kí wọ́n máa ṣiṣẹ́ wẹ́rẹ́wẹ́rẹ́ fún oúnjẹ ti ara wọn.