10 àwọn àgbèrè, àwọn ọkunrin tí ó ń bá ọkunrin lòpọ̀, àwọn gbọ́mọgbọ́mọ, àwọn onírọ́, àwọn tí ó ń búra èké, ati àwọn tí ń ṣe àwọn nǹkan mìíràn tí ó lòdì sí ẹ̀kọ́ tí ó dára,
11 gẹ́gẹ́ bí ìyìn rere tí a fi lé mi lọ́wọ́, ìyìn rere Ọlọrun Ológo, tí ìyìn yẹ fún.
12 Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Kristi Jesu Oluwa wa, ẹni tí ń fún mi ní agbára. Mo dúpẹ́ nítorí ó kà mí yẹ láti fún mi ní iṣẹ́ rẹ̀,
13 èmi tí ó jẹ́ pé tẹ́lẹ̀ rí mo kẹ́gàn rẹ̀, mo ṣe inúnibíni sí i, mo tún fi àbùkù kàn án. Ṣugbọn ó ṣàánú mi nítorí n kò mọ̀ọ́nmọ̀ ṣe é; ninu aigbagbọ ni mo ṣe é.
14 Ṣugbọn oore-ọ̀fẹ́ Oluwa wa pàpọ̀jù lórí mi, ati igbagbọ ati ìfẹ́ tí a ní ninu Kristi Jesu.
15 Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ yìí: ó dájú, ó sì yẹ ní gbígbà tọkàntọkàn, pé Kristi Jesu wá sinu ayé láti gba ẹlẹ́ṣẹ̀ là. Èmi yìí sì ni olórí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.
16 Ìdí tí ó fi ṣàánú mi nìyí, pé èmi ni Kristi Jesu kọ́kọ́ yọ́nú sí ju ẹnikẹ́ni lọ. Mo wá di àpẹẹrẹ gbogbo àwọn tí wọn yóo gbà á gbọ́ tí wọn yóo sì ní ìyè ainipẹkun.