4 ẹni tí ó fẹ́ kí gbogbo eniyan rí ìgbàlà, tí ó sì fẹ́ kí wọn ní ìmọ̀ òtítọ́.
5 Nítorí Ọlọrun kan ni ó wà, alárinà kan ni ó sì wà láàrin Ọlọrun ati eniyan; olúwarẹ̀ ni Kristi Jesu, tí òun náà jẹ́ eniyan,
6 tí ó fi ara rẹ̀ ṣe ìràpadà fún gbogbo eniyan. Èyí ni ẹ̀rí pé, Ọlọrun ṣe ètò pé kí gbogbo eniyan lè ní ìgbàlà nígbà tí àkókò rẹ̀ tó.
7 Òtítọ́ ni mò ń sọ, n kò purọ́, pé ohun tí a yàn mí láti jẹ́ akéde ati aposteli sí ni pé kí n jẹ́ olùkọ́ni fún àwọn tí kì í ṣe Juu nípa nǹkan tí ó jẹ mọ́ igbagbọ ati òtítọ́ Ọlọrun.
8 Nítorí náà mo fẹ́ kí gbogbo eniyan máa gbadura ninu gbogbo ìsìn, kí wọn máa gbé ọwọ́ adura sókè pẹlu ọkàn kan, láìsí èrò ibinu tabi ọkàn àríyànjiyàn.
9 Bákan náà, kí àwọn obinrin wọ aṣọ bí ó ti yẹ, aṣọ tí kò ní ti eniyan lójú, kí wọ́n ṣe ara wọn lọ́ṣọ̀ọ́ níwọ̀ntúnwọ̀nsì. Kí wọn má ṣe di irun wọn ní aláràbarà fún àṣehàn. Kí wọn má ṣe kó ohun ọ̀ṣọ́ bíi wúrà ati ìlẹ̀kẹ̀ tabi aṣọ olówó ńlá sára.
10 Ṣugbọn kí ọ̀ṣọ́ wọn jẹ́ ọpọlọpọ iṣẹ́ rere, bí ó ti yẹ fún àwọn obinrin olùfọkànsìn.