4 ìgbéraga ti sọ irú ẹni bẹ́ẹ̀ di aṣiwèrè, kò sì mọ nǹkankan. Irú ẹni bẹ́ẹ̀ óo fẹ́ràn láti máa ṣe òfintótó ọ̀ràn, ati iyàn jíjà, àwọn ohun tí ó ń mú owú-jíjẹ, ìjà, ìsọkúsọ, ìfura burúkú,
5 ati àríyànjiyàn wá. Nǹkan wọnyi wọ́pọ̀ láàrin àwọn tí orí wọn ti kú, tí wọ́n ti yapa kúrò ní ọ̀nà òtítọ́. Wọ́n rò pé nítorí èrè ni eniyan fi ń ṣe ẹ̀sìn.
6 Òtítọ́ ni pé èrè ńlá wà ninu jíjẹ́ olùfọkànsìn, tí eniyan bá ní ìtẹ́lọ́rùn.
7 Nítorí a kò mú ohunkohun wá sinu ayé, bẹ́ẹ̀ ni a kò lè mú ohunkohun kúrò ninu rẹ̀.
8 Bí a bá ti ní oúnjẹ ati aṣọ, kí á ní ìtẹ́lọ́rùn pẹlu wọn.
9 Àwọn tí wọn ń fẹ́ di ọlọ́rọ̀ a máa ṣubú sinu ìdánwò, tàkúté a sì mú wọn. Wọn a máa lépa ọpọlọpọ nǹkan tí kò mú ọgbọ́n wá ati àwọn nǹkan tí ó lè pa eniyan lára, irú nǹkan tí ó ti mú kí àwọn mìíràn jìn sinu ọ̀fìn ikú ati ìparun.
10 Ìfẹ́ owó ni ìpìlẹ̀ gbogbo nǹkan burúkú. Èyí ni àwọn mìíràn ń lépa tí wọ́n fi ṣìnà kúrò ninu igbagbọ, tí wọ́n sì fi ọwọ́ ara wọn fa ọpọlọpọ ìbànújẹ́ fún ara wọn.