8 Jerusalemu ti da ẹ̀ṣẹ gidigidi, nitorina li o ṣe di ẹni-irira: gbogbo awọn ti mbu ọla fun u kẹgan rẹ̀, nitoripe nwọn ri ihoho rẹ̀: lõtọ on kẹdùn, o si yi ẹ̀hin pada.
9 Ẽri rẹ̀ wà ni iṣẹti aṣọ rẹ̀; on kò si ranti opin rẹ̀ ikẹhin; nitorina ni o ṣe sọkalẹ ni isọkalẹ iyanu: kò ni olutunu, Oluwa, wò ipọnju mi, nitori ọta ti bori!
10 Aninilara ti nà ọwọ rẹ̀ jade sori gbogbo ohun daradara rẹ̀: nitori on ti ri pe awọn orilẹ-ède wọ ibi-mimọ́ rẹ̀, eyiti iwọ paṣẹ pe, nwọn kì o wọ inu ijọ tirẹ.
11 Gbogbo awọn enia rẹ̀ kẹdùn, nwọn wá onjẹ; nwọn fi ohun daradara fun onjẹ lati tu ara wọn ninu. Wò o, Oluwa, ki o si rò! nitori emi di ẹni-ẹ̀gan.
12 Kò ha kàn nyin bi, gbogbo ẹnyin ti nkọja? Wò o, ki ẹ si ri bi ibanujẹ kan ba wà bi ibanujẹ mi, ti a ṣe si mi! eyiti Oluwa fi pọn mi loju li ọjọ ibinu gbigbona rẹ̀.
13 Lati oke li a ti rán iná sinu egungun mi, o si ràn ninu rẹ̀: On ti nà àwọn fun ẹsẹ mi, o ti yi mi pada sẹhin; O ti mu mi dahoro, mo si rẹ̀wẹsi lojojumọ.
14 Okùn àjaga irekọja mi li a dimu li ọwọ rẹ̀; a so wọn pọ̀: nwọn yi ọrùn mi ka, nwọn tẹ agbara mi mọlẹ; Oluwa ti fi mi le ọwọ awọn ẹniti emi kò le dide si.