Ẹk. Jer 5 YCE

Adura fún Àánú

1 RANTI, Oluwa, ohun ti o de sori wa; rò ki o si wò ẹ̀gan wa!

2 A fi ogún wa le awọn alejo lọwọ, ile wa fun awọn ajeji.

3 Awa jẹ alaini obi, baba kò si, awọn iyá wa dabi opó.

4 Awa ti fi owo mu omi wa; a nta igi wa fun wa.

5 Awọn ti nlepa wa sunmọ ọrùn wa: ãrẹ̀ mu wa, awa kò si ni isimi.

6 Awa ti fi ọwọ wa fun awọn ara Egipti, ati fun ara Assiria, lati fi onjẹ tẹ́ wa lọrùn.

7 Awọn baba wa ti ṣẹ̀, nwọn kò si sí; awa si nrù aiṣedede wọn.

8 Awọn ẹrú ti jọba lori wa: ẹnikan kò si gbà wa kuro li ọwọ wọn.

9 Ninu ewu ẹmi wa li awa nlọ mu onjẹ wa, nitori idà ti aginju.

10 Àwọ wa pọ́n gẹgẹ bi àro nitori gbigbona ìyan na.

11 Nwọn tẹ́ awọn obinrin li ogo ni Sioni, awọn wundia ni ilu Juda.

12 A so awọn ijoye rọ̀ nipa ọwọ wọn: a kò buyin fun oju awọn àgbagba.

13 Awọn ọdọmọkunrin ru ọlọ, ãrẹ̀ mu awọn ọmọde labẹ ẹrù-igi.

14 Awọn àgbagba dasẹ kuro li ẹnu-bode, awọn ọdọmọkunrin kuro ninu orin wọn.

15 Ayọ̀ ọkàn wa ti dá; a yi ijo wa pada si ọ̀fọ.

16 Ade ṣubu kuro li ori wa: ègbe ni fun wa, nitori awa ti ṣẹ̀.

17 Nitori eyi li ọkàn wa rẹ̀wẹsi; nitori nkan wọnyi oju wa di baibai.

18 Nitori oke Sioni, ti dahoro, awọn kọ̀lọkọlọ nrin lori rẹ̀.

19 Iwọ, Oluwa, li o wà lailai; itẹ́ rẹ lati iran de iran!

20 Ẽṣe ti iwọ fi gbagbe wa lailai, ti o si kọ̀ wa silẹ li ọjọ pipẹ?

21 Oluwa, yi wa pada sọdọ rẹ, awa o si yipada; sọ ọjọ wa di ọtun gẹgẹ bi ti igbãni.

22 Tabi iwọ ha ti kọ̀ wa silẹ patapata, tobẹ̃ ti iwọ si binu si wa gidigidi?

orí

1 2 3 4 5