Ẹk. Jer 3 YCE

Ìjìyà, Ìrònúpìwàdà ati Ìrètí

1 EMI ni ọkunrin na ti o ti ri wàhala nipa ọpa ibinu rẹ̀.

2 O ti fà mi, o si mu mi wá sinu òkunkun, kì si iṣe sinu imọlẹ.

3 Lõtọ, o yi ọwọ rẹ̀ pada si mi siwaju ati siwaju li ọjọ gbogbo.

4 O ti sọ ẹran-ara mi ati àwọ mi di ogbó, o ti fọ́ egungun mi.

5 O ti mọdi tì mi, o fi orõrò ati ãrẹ̀ yi mi ka.

6 O ti fi mi si ibi òkunkun, bi awọn ti o ti kú pẹ.

7 O ti sọgba yi mi ka, ti emi kò le jade; o ti ṣe ẹ̀wọn mi wuwo

8 Bi emi ti kigbe pẹlu, ti emi si npariwo, o sé adura mi mọ.

9 O ti fi okuta gbigbẹ sọgba yi ọ̀na mi ka, o ti yi ipa ọ̀na mi po.

10 On jẹ bi ẹranko beari ti o ba dè mi, bi kiniun ni ibi ìkọkọ.

11 O ti mu mi ṣina li ọ̀na mi, o si fà mi ya pẹrẹpẹrẹ: o ti sọ mi di ahoro.

12 O ti fà ọrun rẹ̀, o si fi mi ṣe itasi fun ọfa rẹ̀.

13 O ti mu ki ọfà apó rẹ̀ wọ inu-ẹdọ mi lọ.

14 Emi jẹ ẹni ẹsin fun gbogbo enia mi; orin wọn ni gbogbo ọjọ.

15 O ti fi ìkoro mu mi yo, o ti mu mi mu omi wahala.

16 O ti fi ọta ṣẹ́ ehín mi, o tẹ̀ mi mọlẹ ninu ẽru.

17 Iwọ si ti mu ọkàn mi jina réré si alafia; emi gbagbe rere.

18 Emi si wipe, Agbara mi ati ireti mi ṣègbe kuro lọdọ Oluwa.

19 Ranti wahala mi ati inilara mi, ani ìkoro ati orõro.

20 Lõtọ, nigbati ọkàn mi nṣe iranti wọn, o si tẹriba ninu mi.

21 Eyi ni emi o rò li ọkàn mi, nitorina emi o ma reti.

22 Ãnu Oluwa ni, ti awa kò parun tan, nitori irọnu-ãnu rẹ kò li opin.

23 Ọtun ni li orowurọ; titobi ni otitọ rẹ.

24 Oluwa ni ipin mi, bẹ̃li ọkàn mi wi; nitorina ni emi ṣe reti ninu rẹ̀.

25 Oluwa ṣe rere fun gbogbo ẹniti o duro dè e, fun ọkàn ti o ṣafẹri rẹ̀.

26 O dara ti a ba mã reti ni idakẹjẹ fun igbala Oluwa.

27 O dara fun ọkunrin, ki o gbe àjaga ni igba-ewe rẹ̀.

28 Ki o joko on nikan, ki o si dakẹ, nitori Ọlọrun ti gbe e le ori rẹ̀.

29 Ki o fi ẹnu rẹ̀ sinu ẽkuru; pe bọya ireti le wà:

30 Ki o fi ẹ̀rẹkẹ fun ẹniti o lù u; ki o kún fun ẹ̀gan patapata.

31 Nitoriti Oluwa kì yio ṣá ni tì lailai:

32 Bi o tilẹ mu ibanujẹ wá, sibẹ on o ni irọnu gẹgẹ bi ọ̀pọlọpọ ãnu rẹ̀.

33 Nitori on kì ifẹ ipọn-ni-loju lati ọkàn rẹ̀ wá, bẹ̃ni kì ibà ọmọ enia ninu jẹ.

34 Lati tẹ̀ gbogbo ara-tubu ilẹ-aiye mọlẹ li abẹ ẹsẹ rẹ̀.

35 Lati yi ẹ̀tọ enia sapakan niwaju Ọga-ogo julọ.

36 Lati yi ọ̀ran idajọ enia pada, Oluwa kò fẹ ri i?

37 Tali ẹniti iwi, ti isi iṣẹ, nigbati Oluwa kò paṣẹ rẹ̀.

38 Ibi ati rere kò ha njade lati ẹnu Ọga-ogo-julọ wá?

39 Ẽṣe ti enia alãye nkùn? ti o wà lãye, ki olukuluku ki o kùn nitori ẹ̀ṣẹ rẹ̀!

40 Jẹ ki a wádi, ki a si dán ọ̀na wa wò, ki a si tun yipada si Oluwa.

41 Jẹ ki a gbe ọkàn ati ọwọ wa soke si Ọlọrun li ọrun.

42 Awa ti dẹṣẹ, a si ti ṣọtẹ: iwọ kò ti dariji.

43 Iwọ ti fi ibinu bora, o si ṣe inunibini si wa: iwọ ti pa, o kò si ti dasi.

44 Iwọ ti fi awọsanma bo ara rẹ, ki adura má le là kọja.

45 Iwọ ti ṣe wa bi idarọ ati ohun alainilãri li ãrin awọn orilẹ-ède.

46 Gbogbo awọn ọta wa ti ya ẹnu wọn si wa.

47 Ẹ̀ru ati ọ̀fin wá sori wa, idahoro ati iparun.

48 Oju mi fi odò omi ṣan silẹ, nitori iparun ọmọbinrin awọn enia mi.

49 Oju mi dà silẹ ni omije, kò si dá, laiṣe isimi.

50 Titi Oluwa fi wò ilẹ, ti o wò lati ọrun wá,

51 Oju mi npọn ọkàn mi loju, nitori gbogbo awọn ọmọbinrin ilu mi.

52 Awọn ọta mi dẹkùn fun mi gidigidi, gẹgẹ bi fun ẹiyẹ laini idi.

53 Nwọn ti ke ẹmi mi kuro ninu iho, nwọn si yi okuta sori mi.

54 Nwọn mu omi ṣan lori mi; emi wipe, Mo gbe!

55 Emi kepe orukọ rẹ, Oluwa, lati iho jijin wá.

56 Iwọ ti gbọ́ ohùn mi: máṣe se eti rẹ mọ si imikanlẹ mi, si igbe mi.

57 Iwọ sunmọ itosi li ọjọ ti emi kigbe pè ọ: iwọ wipe: Má bẹ̀ru!

58 Oluwa, iwọ ti gba ijà mi jà; iwọ ti rà ẹmi mi pada.

59 Oluwa, iwọ ti ri inilara mi, ṣe idajọ ọran mi!

60 Iwọ ti ri gbogbo igbẹsan wọn, gbogbo èro buburu wọn si mi.

61 Iwọ ti gbọ́ ẹ̀gan wọn, Oluwa, gbogbo èro buburu wọn si mi.

62 Ète awọn wọnni ti o dide si mi, ati ipinnu wọn si mi ni gbogbo ọjọ.

63 Kiyesi ijoko wọn ati idide wọn! emi ni orin-ẹsin wọn.

64 San ẹsan fun wọn, Oluwa, gẹgẹ bi iṣẹ ọwọ wọn!

65 Fun wọn ni ifọju ọkàn, ègun rẹ lori wọn!

66 Fi ibinu lepa wọn, ki o si pa wọn run kuro labẹ ọrun Oluwa!

orí

1 2 3 4 5