18 Ọkàn wọn kigbe si Oluwa, iwọ odi ọmọbinrin Sioni, jẹ ki omije ṣan silẹ gẹgẹ bi odò lọsan ati loru; má fun ara rẹ ni isimi; máṣe jẹ ki ẹyin oju rẹ gbe jẹ.
19 Dide, kigbe soke li oru ni ibẹrẹ akoko iṣọ: tú ọkàn rẹ jade gẹgẹ bi omi niwaju Oluwa: gbe ọwọ rẹ soke si i fun ẹmi awọn ọmọ wẹwẹ rẹ, ti nkulọ fun ebi ni gbogbo ori-ita.
20 Wò o, Oluwa, ki o rò, fun tani iwọ ti ṣe eyi? Awọn obinrin ha le ma jẹ eso-inu wọn, awọn ọmọ-ọwọ ti nwọn npọ̀n? a ha le ma pa alufa ati woli ni ibi mimọ́ Oluwa?
21 Ewe ati arugbo dubulẹ ni ita wọnni: awọn wundia mi ati awọn ọdọmọkunrin mi ṣubu nipa idà: iwọ ti pa li ọjọ ibinu rẹ; iwọ ti pa, iwọ kò si dasi.
22 Iwọ ti kepe ẹ̀ru mi yikakiri gẹgẹ bi li ọjọ mimọ́, tobẹ̃ ti ẹnikan kò sala tabi kì o kù li ọjọ ibinu Oluwa: awọn ti mo ti pọ̀n ti mo si tọ́, ni ọta mi ti run.