3 Ọlọrun yio ti Temani wá, ati Ẹni Mimọ́ lati oke Parani. Ogo rẹ̀ bò awọn ọrun, ilẹ aiye si kun fun iyìn rẹ̀.
4 Didán rẹ̀ si dabi imọlẹ; itanṣan nti iha rẹ̀ wá: nibẹ̀ si ni ipamọ agbara rẹ̀ wà.
5 Ajàkalẹ arùn nlọ niwaju rẹ̀, ati okunrun njade lati ẹsẹ̀ rẹ̀ lọ.
6 O duro, o si wọ̀n ilẹ aiye: o wò, o si mu awọn orilẹ-ède warìri; a si tú awọn oke-nla aiyeraiye ká, awọn òkèkékèké aiyeraiye si tẹba: ọ̀na rẹ̀ aiyeraiye ni.
7 Mo ri agọ Kuṣani labẹ ipọnju: awọn aṣọ-ikele ilẹ̀ Midiani si warìri.
8 Oluwa ha binu si awọn odò? ibinu rẹ̀ ha wà si awọn odò? ibinu rẹ̀ ha wà si okun, ti iwọ fi ngùn ẹṣin rẹ ati kẹkẹ́ igbàla rẹ?
9 A ṣi ọrun rẹ̀ silẹ patapata, gẹgẹ bi ibura awọn ẹ̀ya, ani ọ̀rọ rẹ. Iwọ ti fi odò là ilẹ aiye.