Hag 2 YCE

Ẹwà Tẹmpili Tuntun náà

1 LI oṣù keje, li ọjọ kọkanlelogun oṣù na, ni ọ̀rọ Oluwa wá nipa ọwọ́ Hagai woli, wipe,

2 Sọ nisisiyi fun Serubbabeli ọmọ Ṣealtieli, bãlẹ Juda, ati fun Joṣua, ọmọ Josedeki, olori alufa, ati fun awọn enia iyokù pe,

3 Tali o kù ninu nyin ti o ti ri ile yi li ogo rẹ̀ akọṣe? bawo li ẹnyin si ti ri i si nisisiyi? kò ha dàbi asan loju nyin bi a fi ṣe akawe rẹ̀?

4 Ṣugbọn nisisiyi mura giri, Iwọ Serubbabeli, li Oluwa wi, ki o si mura giri, Iwọ Joṣua, ọmọ Josedeki, olori alufa; ẹ si mura giri gbogbo ẹnyin enia ilẹ na, li Oluwa wi, ki ẹ si ṣiṣẹ: nitori emi wà pẹlu nyin, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi.

5 Gẹgẹ bi ọ̀rọ ti mo ba nyin dá majẹmu nigbati ẹnyin ti Egipti jade wá, bẹ̃ni ẹmi mi wà lãrin nyin: ẹ máṣe bẹ̀ru.

6 Nitori bayi ni Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, pe, Ẹ̃kan ṣa, nigbà diẹ si i, li emi o mì awọn ọrun, ati aiye, ati okun, ati iyàngbẹ ilẹ.

7 Emi o si mì gbogbo orilẹ-ède, ifẹ gbogbo orilẹ-ède yio si de: emi o si fi ogo kún ile yi, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi.

8 Temi ni fàdakà, temi si ni wurà, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi.

9 Ogo ile ikẹhìn yi yio pọ̀ jù ti iṣãju lọ, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi: nihinyi li emi o si fi alafia fun ni, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi.

Wolii náà Lọ Bá Àwọn Àlùfáà Jíròrò

10 Li ọjọ ikẹrinlelogun oṣù kẹsan, li ọdun keji Dariusi, li ọ̀rọ Oluwa wá nipa Hagai woli, pe,

11 Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi; bère ofin lọwọ awọn alufa nisisiyi, pe,

12 Bi ẹnikan ba rù ẹran mimọ́ ni iṣẹti aṣọ rẹ̀, ti o si fi iṣẹti aṣọ rẹ̀ kan àkara, tabi àṣaró, tabi ọti-waini, tabi ororo, tabi ẹrankẹran, yio ha jẹ mimọ́? Awọn alufa si dahùn wipe, Bẹ̃kọ.

13 Hagai si wipe, Bi ẹnikan ti o ba jẹ alaimọ́ nipa okú ba fi ara kan ọkan ninu wọnyi, yio ha jẹ alaimọ́? Awọn alufa si dahùn wipe, Yio jẹ alaimọ́.

14 Nigbana ni Hagai dahùn o si wipe, Bẹ̃ni enia wọnyi ri, bẹ̃ si ni orilẹ-ède yi ri niwaju mi, li Oluwa wi; bẹ̃ si li olukuluku iṣẹ ọwọ wọn; eyiti nwọn si fi rubọ nibẹ̀ jẹ alaimọ́.

OLUWA Ṣe Ìlérí Ibukun

15 Njẹ nisisiyi, mo bẹ̀ nyin, ẹ rò lati oni yi de atẹhìnwa, ki a to fi okuta kan le ori ekeji ninu tempili Oluwa;

16 Lati ọjọ wọnni wá, nigbati ẹnikan bã de ibi ile ogun, mẹwa pere ni: nigbati ẹnikan ba de ibi ifunti lati bã gbọ́n ãdọta akoto ninu ifunti na, ogún pere ni.

17 Mo fi ìrẹdanù ati imúwòdu ati yìnyin lù nyin ninu gbogbo iṣẹ ọwọ nyin: ṣugbọn ẹnyin kò yipadà sọdọ mi, li Oluwa wi.

18 Nisisiyi ẹ rò lati oni lọ de atẹhìnwa, lati ọjọ ikẹrinlelogun oṣù kẹsan, ani lati ọjọ ti a ti fi ipilẹ tempili Oluwa sọlẹ, ro o.

19 Eso ha wà ninu abà bi? lõtọ, àjara, ati igi òpọtọ, ati pomegranate, ati igi olifi, kò iti so sibẹ̀sibẹ̀: lati oni lọ li emi o bukún fun nyin.

Ìlérí OLUWA fún Serubabeli

20 Ọ̀rọ Oluwa si tún tọ̀ Hagai wá li ọjọ kẹrinlelogun oṣù na pe,

21 Sọ fun Serubbabeli, bãlẹ Juda, pe, emi o mì awọn ọrun ati aiye;

22 Emi o si bì itẹ awọn ijọba ṣubu, emi o si pa agbara ijọba keferi run; emi o si doju awọn kẹkẹ́ de, ati awọn ti o gùn wọn; ati ẹṣin ati awọn ẹlẹṣin yio wá ilẹ; olukuluku nipa idà arakunrin rẹ̀.

23 Li ọjọ na, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, li emi o mu ọ, Iwọ Serubbabeli, iranṣẹ mi, ọmọ Ṣealtieli, li Oluwa wi, emi o si sọ ọ di oruka edídi kan: nitoriti mo ti yàn ọ, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi.

orí

1 2