Mal 1 YCE

1 Ọ̀RỌ-ÌMỌ ọ̀rọ Oluwa si Israeli nipa ọwọ Malaki.

Ìfẹ́ OLUWA sí Israẹli

2 Emi ti fẹ nyin, li Oluwa wi. Ṣugbọn ẹnyin wipe, Ninu kili o fẹ wa? Arakunrin Jakobu ki Esau iṣe? li Oluwa wi: bẹli emi sa fẹ Jakobu,

3 Mo si korira Esau, mo si sọ awọn oke-nla rẹ̀ ati ilẹ nini rẹ̀ di ahoro fun awọn dragoni aginjù.

4 Nitori Edomu wipe, A run wa tan, ṣugbọn awa o padà, a si kọ ibùgbe ahoro wọnni; bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi; Nwọn o kọ, ṣugbọn emi o wo lulẹ; Nwọn o si pe wọn ni, Agbègbe ìwa buburu, ati awọn enia ti Oluwa ni ikọnnu si titi lai.

5 Oju nyin o si ri, ẹnyin o si wipe, A o gbe Oluwa ga lati oke agbègbe Israeli wá.

OLUWA Bá Àwọn àlùfáàa Wí

6 Ọmọ a ma bọla fun baba, ati ọmọ-ọdọ fun oluwa rẹ̀: njẹ bi emi ba ṣe baba, ọla mi ha da? bi emi ba si ṣe oluwa, ẹ̀ru mi ha da? li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi fun nyin: Ẹnyin alufa, ti ngàn orukọ mi. Ẹnyin si wipe, Ninu kini awa fi kẹ́gàn orukọ rẹ?

7 Ẹnyin fi akarà aimọ́ rubọ lori pẹpẹ mi; ẹnyin si wipe, Ninu kini awa ti sọ ọ di aimọ́? Ninu eyi ti ẹnyin wipe, Tabili Oluwa di ohun ẹgàn.

8 Bi ẹnyin ba si fi eyi ti oju rẹ̀ fọ́ rubọ, ibi kọ́ eyini? bi ẹnyin ba si fi amúkun ati olokunrùn rubọ, ibi kọ́ eyini? mu u tọ bãlẹ rẹ lọ nisisiyi; inu rẹ̀ yio ha dùn si ọ, tabi yio ha kà ọ si? li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi.

9 Njẹ nisisiyi, mo bẹ̀ nyin, ẹ bẹ̀ Ọlọrun ki o ba le ṣe ojurere si wa: lati ọwọ nyin li eyi ti wá: on o ha kà nyin si? li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi.

10 Ta si ni ninu nyin ti yio se ilẹkun? bẹ̃li ẹnyin kò da iná asan lori pẹpẹ mi mọ. Emi kò ni inu-didùn si nyin, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, bẹ̃li emi kì yio gba ọrẹ kan lọwọ nyin.

11 Nitori lati ilã-õrùn titi o si fi de iwọ̀ rẹ̀, orukọ mi yio tobi lãrin awọn keferi; nibi gbogbo li a o si fi turàri jona si orukọ mi, pẹlu ọrẹ mimọ́: nitori orukọ mi o tobi lãrin awọn keferi, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi.

12 Nitori ẹnyin ti sọ ọ di aimọ́, ninu eyi ti ẹ wipe, Tabili Oluwa di aimọ́; ati eso rẹ̀, ani onjẹ rẹ̀ ni ohun ẹ̀gan.

13 Ẹnyin wi pẹlu pe, Wo o agara kili eyi! ẹnyin ṣitìmú si i, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi; ẹnyin si mu eyi ti o ya, ati arọ, ati olokunrùn wá; bayi li ẹnyin mu ọrẹ wá: emi o ha gbà eyi lọwọ nyin? li Oluwa wi.

14 Ṣugbọn ifibu ni fun ẹlẹtàn na, ti o ni akọ ninu ọwọ́-ẹran rẹ̀, ti o si ṣe ileri ti o si fi ohun abùku rubọ si Oluwa; nitori Ọba nla li emi, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, ẹ̀ru si li orukọ mi lãrin awọn keferi.

orí

1 2 3 4