1 KIYESI i, ọjọ Oluwa mbọ̀, a o si pin ikogun rẹ lãrin rẹ.
2 Nitori emi o kó gbogbo orilẹ-ède jọ si Jerusalemu fun ogun; a o si kó ilu na, a o si kó awọn ile, a o si bà awọn obinrin jẹ, abọ̀ ilu na yio lọ si igbèkun, a kì yio si ké iyokù awọn enia na kuro ni ilu na.
3 Nigbana ni Oluwa yio jade lọ, yio si ba awọn orilẹ-ède wọnni jà, gẹgẹ bi iti ijà li ọjọ ogun.
4 Ẹsẹ̀ rẹ̀ yio si duro li ọjọ na lori oke Olifi, ti o wà niwaju Jerusalemu ni ila-õrun, oke Olifi yio si là meji si ihà ila-õrun ati si ihà iwọ̀-õrun, afonifojì nlanla yio wà: idajì oke na yio si ṣi sihà ariwa, ati idajì rẹ̀ siha gusu.
5 Ẹnyin o si sá si afonifojì oke mi wọnni: nitoripe afonifoji oke na yio de Asali: nitõtọ, ẹnyin o sa bi ẹ ti sa fun ìṣẹ̀lẹ̀ nì li ọjọ Ussiah ọba Juda: Oluwa Ọlọrun mi yio si wá, ati gbogbo awọn Ẹni-mimọ́ pẹlu rẹ̀.
6 Yio si ṣe li ọjọ na, imọlẹ kì yio mọ́, bẹ̃ni kì yio ṣõkùnkun.
7 Ṣugbọn yio jẹ ọjọ kan mimọ̀ fun Oluwa, kì iṣe ọsan, kì iṣe oru; ṣugbọn yio ṣe pe, li aṣãlẹ imọlẹ yio wà.
8 Yio si ṣe li ọjọ na, omi iyè yio ti Jerusalemu ṣàn lọ; idajì wọn sihà kun ilà-õrun, ati idajì wọn sihà okun ẹhìn: nigbà ẹ̀run ati nigbà otutù ni yio ri bẹ̃.
9 Oluwa yio si jọba lori gbogbo aiye: li ọjọ na ni Oluwa kan yio wà, orukọ rẹ̀ yio si jẹ ọkan.
10 A o yi gbogbo ilẹ padà bi pẹtẹlẹ kan lati Geba de Rimmoni lapa gusu Jerusalemu: a o si gbe e soke, yio si gbe ipò rẹ̀, lati ibode Benjamini titi de ibi ibode ekini, de ibode igun nì, ati lati ile iṣọ Hananeeli de ibi ifunti waini ọba.
11 Enia yio si ma gbe ibẹ̀, kì yio si si iparun yanyan mọ; Ṣugbọn a o ma gbe Jerusalemu lailewu.
12 Eyi ni yio si jẹ àrun ti Oluwa yio fi kọlu gbogbo awọn enia ti o ti ba Jerusalemu ja; ẹran-ara wọn yio rù nigbati wọn duro li ẹsẹ̀ wọn, oju wọn yio si rà ni ihò wọn, ahọn wọn yio si jẹrà li ẹnu wọn.
13 Yio si ṣe li ọjọ na, irọkẹ̀kẹ nla lati ọdọ Oluwa wá yio wà lãrin wọn; nwọn o si dì ọwọ ara wọn mu, ọwọ rẹ̀ yio si dide si ọwọ ẹnikeji rẹ̀.
14 Juda pẹlu yio si jà ni Jerusalemu; ọrọ̀ gbogbo awọn keferi ti o wà kakiri li a o si kojọ, wurà, ati fàdakà, ati aṣọ, li ọpọlọpọ.
15 Bẹ̃ni àrun ẹṣin, ibãka, ràkumi, ati ti kẹtẹkẹtẹ, yio si wà, ati gbogbo ẹranko ti mbẹ ninu agọ wọnyi gẹgẹ bi àrun yi.
16 Yio si ṣe, olukuluku ẹniti o kù ninu gbogbo awọn orilẹ-ède ti o dide si Jerusalemu yio ma goke lọ lọdọdun lati sìn Ọba, Oluwa awọn ọmọ-ogun, ati lati pa àse agọ wọnni mọ.
17 Yio si ṣe, ẹnikẹni ti kì yio goke wá ninu gbogbo idile aiye si Jerusalemu lati sìn Ọba, Oluwa awọn ọmọ-ogun, fun wọn ni òjo kì yio rọ̀.
18 Bi idile Egipti kò ba si goke lọ, ti nwọn kò si wá, ti kò ni òjo; àrun na yio wà, ti Oluwa yio fi kọlù awọn keferi ti kò goke wá lati pa àse agọ na mọ.
19 Eyi ni yio si jẹ iyà Egipti, ati iyà gbogbo orilẹ-ède ti kò goke wá lati pa àse agọ mọ.
20 Li ọjọ na ni MIMỌ SI OLUWA yio wà lara ṣaworo ẹṣin; ati awọn ikòko ni ile Oluwa yio si dàbi awọn ọpọ́n wọnni niwaju pẹpẹ.
21 Nitõtọ, gbogbo ikòko ni Jerusalemu ati ni Juda yio jẹ mimọ́ si Oluwa awọn ọmọ-ogun: ati gbogbo awọn ti nrubọ yio wá, nwọn o si gbà ninu wọn, nwọn o si bọ̀ ninu rẹ̀: li ọjọ na ni ara Kenaani kì yio si si mọ ni ile Oluwa awọn ọmọ-ogun.