Sek 10 YCE

OLUWA Ṣèlérí láti Gba Àwọn Eniyan Rẹ̀ Là

1 Ẹ bère òjo nigba arọ̀kuro li ọwọ Oluwa; Oluwa yio kọ mànamána, yio si fi ọ̀pọ òjò fun wọn, fun olukulukù koriko ni pápa.

2 Nitori awọn oriṣa ti nsọ̀rọ asan, awọn alafọṣẹ si ti ri eké, nwọn si ti rọ́ alá eké; nwọn ntù ni ni inu lasan, nitorina nwọn ba ti wọn lọ bi ọwọ́ ẹran, a ṣẹ wọn niṣẹ, nitori darandaran kò si.

3 Ibinu mi ru si awọn darandaran, mo si jẹ awọn ewurẹ ni iyà; nitori Oluwa awọn ọmọ-ogun ti bẹ̀ agbo rẹ̀ ile Juda wò, o si fi wọn ṣe bi ẹṣin rẹ̀ daradara li ogun.

4 Lati ọdọ rẹ̀ ni igun ti jade wá, lati ọdọ rẹ̀ ni iṣo ti wá, lati ọdọ rẹ̀ ni ọrun ogun ti wá, lati ọdọ rẹ̀ ni awọn akoniṣiṣẹ gbogbo ti wá.

5 Nwọn o si dabi awọn alagbara, ti ntẹ́ ẹrẹ̀ ita ni mọlẹ li ogun: nwọn o si jagun, nitori Oluwa wà pẹlu wọn nwọn o si doju tì awọn ti ngùn ẹṣin.

6 Emi o si mu ile Juda le, emi o si gbà ile Josefu là, emi o si tún mu wọn joko; nitori mo ti ṣãnu fun wọn, nwọn o si dabi ẹnipe emi kò ti ta wọn nù: nitori emi ni Oluwa Ọlọrun wọn, emi o si gbọ́ ti wọn.

7 Efraimu yio si ṣe bi alagbara, ọkàn wọn yio si yọ̀ bi ẹnipe nipa ọti-waini: ani awọn ọmọ wọn yio ri i, nwọn o si yọ̀, inu wọn o si dùn si Oluwa.

8 Emi o kọ si wọn, emi o si ṣà wọn jọ; nitori emi ti rà wọn pada: nwọn o si rẹ̀ si i gẹgẹ bi wọn ti nrẹ̀ si i ri.

9 Emi o si gbìn wọn lãrin awọn enia: nwọn o si ranti mi ni ilẹ jijin; nwọn o si wà pẹlu awọn ọmọ wọn, nwọn o si tún pada.

10 Emi o si tún mu wọn pada kuro ni ilẹ Egipti pẹlu, emi o si ṣà wọn jọ kuro ni ilẹ Assiria: emi o si mu wọn wá si ilẹ Gileadi ati Lebanoni; a kì yio si ri àye fun wọn.

11 Yio si là okun wahala ja, yio si lù riru omi ninu okun, gbogbo ibu odò ni yio si gbẹ, a o si rẹ̀ igberaga Assiria silẹ, ọpa alade Egipti yio si lọ kuro.

12 Emi o si mu wọn le ninu Oluwa; nwọn o si rìn soke rìn sodò li orukọ rẹ̀, ni Oluwa wi.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14