Sek 2 YCE

Ìran nípa Okùn Ìwọ̀n

1 MO si tun gbe oju mi soke, mo si wò, si kiyesi i, ọkunrin kan ti on ti okùn-iwọ̀n lọwọ rẹ̀.

2 Mo si wipe, Nibo ni iwọ nlọ? o si wi fun mi pe, Lati wọ̀n Jerusalemu, lati ri iye ibú rẹ̀, ati iye gigùn rẹ̀.

3 Si kiyesi i, angeli ti o mba mi sọ̀rọ jade lọ, angeli miran si jade lọ ipade rẹ̀.

4 O si wi fun u pe, Sare, sọ fun ọdọmọkunrin yi wipe, a o gbe inu Jerusalemu bi ilu ti kò ni odi nitori ọ̀pọ enia ati ohun-ọsìn inu rẹ̀:

5 Oluwa wipe, Emi o si jẹ odi iná fun u yika, emi o si jẹ ogo lãrin rẹ̀.

Pípe Àwọn tí A kó lẹ́rú pada Wálé

6 Ã! ã! sá kuro ni ilẹ ariwa, ni Oluwa wi; nitoripe bi afẹfẹ mẹrin ọrun ni mo tu nyin kakiri, ni Oluwa wi.

7 Sioni, gba ara rẹ là, iwọ ti o mba ọmọbinrin Babiloni gbe.

8 Nitori bayi ni Oluwa awọn ọmọ-ogun wi; lẹhìn ogo li o ti rán mi si awọn orilẹ-ède ti nkó nyin: nitori ẹniti o tọ́ nyin, o tọ́ ọmọ oju rẹ̀.

9 Nitori kiyesi i, emi o gbọ̀n ọwọ mi si ori wọn, nwọn o si jẹ ikogun fun iranṣẹ wọn: ẹnyin o si mọ̀ pe, Oluwa awọn ọmọ-ogun li o rán mi.

10 Kọrin ki o si yọ̀, iwọ ọmọbinrin Sioni: sa wò o, mo de, emi o si gbe ãrin rẹ, ni Oluwa wi.

11 Ọ̀pọlọpọ orilẹ-ède ni yio dapọ̀ mọ Oluwa li ọjọ na, nwọn o si di enia mi; emi o si gbe ãrin rẹ, iwọ o si mọ̀ pe, Oluwa awọn ọmọ-ogun li o rán mi si ọ.

12 Oluwa o si jogún Juda iní rẹ̀, nilẹ̀ mimọ́, yio si tun yàn Jerusalemu.

13 Ẹ dakẹ, gbogbo ẹran-ara niwaju Oluwa: nitori a ji i lati ibùgbe mimọ́ rẹ̀ wá.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14