Sek 6 YCE

Ìran nípa Àwọn Kẹ̀kẹ́ Ogun Mẹrin

1 MO si yipadà, mo si gbe oju mi soke, mo si wò, si kiyesi i, kẹkẹ́ mẹrin jade wá lati ãrin oke-nla meji; awọn oke-nla na si jẹ oke-nla idẹ.

2 Awọn ẹṣin pupa wà ni kẹkẹ́ ekini; ati awọn ẹṣin dudu ni kẹkẹ́ keji;

3 Ati awọn ẹṣin funfun ni kẹkẹ́ kẹta; ati awọn adikalà ati alagbara ẹṣin ni kẹkẹ́ kẹrin.

4 Mo si dahùn mo si wi fun angeli ti mba mi sọ̀rọ pe, Kini wọnyi, oluwa mi?

5 Angeli na si dahùn o si wi fun mi pe, Wọnyi ni awọn ẹmi mẹrin ti ọrun, ti njade lọ kuro ni iduro niwaju Oluwa gbogbo aiye.

6 Awọn ẹṣin dudu ti o wà ninu rẹ̀ jade lọ si ilẹ ariwa; awọn funfun si jade tẹ̀le wọn; awọn adíkalà si jade lọ si ihà ilẹ gusù.

7 Awọn alagbara ẹṣin si jade lọ, nwọn si nwá ọ̀na ati lọ ki nwọn ba le rìn sihin sọhun li aiye; o si wipe, Ẹ lọ, ẹ lọ irìn sihin sọhun li aiye. Nwọn si rìn sihin sọhun li aiye.

8 Nigbana ni on si kọ́ si mi, o si ba mi sọ̀rọ, wipe, Wò o, awọn wọnyi ti o lọ sihà ilẹ ariwa ti mu ẹmi mi parọrọ ni ilẹ ariwa.

Àṣẹ nípa ati Dé Joṣua ládé

9 Ọ̀rọ Oluwa si tọ̀ mi wá, wipe,

10 Mu ninu igbèkun, ninu awọn ti Heldai, ti Tobijah, ati ti Jedaiah, ti o ti Babiloni de, ki iwọ si wá li ọjọ kanna, ki o si wọ ile Josiah ọmọ Sefaniah lọ;

11 Ki o si mu fàdakà ati wurà, ki o si fi ṣe ade pupọ̀, ki o si gbe wọn kà ori Joṣua ọmọ Josedeki, olori alufa:

12 Si sọ fun u pe, Bayi ni Oluwa awọn ọmọ-ogun sọ wipe, Wò ọkunrin na ti orukọ rẹ̀ njẹ ẸKA; yio si yọ ẹka lati abẹ rẹ̀ wá, yio si kọ́ tempili Oluwa;

13 On ni yio si kọ́ tempili Oluwa; on ni yio si rù ogo, yio si joko yio si jọba lori itẹ rẹ̀; on o si jẹ alufa lori itẹ̀ rẹ̀; ìmọ alafia yio si wà lãrin awọn mejeji.

14 Ade wọnni yio si wà fun Helemu, ati fun Tobijah, ati fun Jedaiah, ati fun Heni, ọmọ Sefaniah, fun iranti ni tempili Oluwa.

15 Awọn ti o jìna rére yio wá ikọle ni tempili Oluwa, ẹnyin o si mọ̀ pe, Oluwa awọn ọmọ-ogun ti rán mi si nyin. Yio si ri bẹ, bi ẹnyin o ba gbà ohùn Oluwa Ọlọrun nyin gbọ́ nitõtọ.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14