1 ANGELI ti o mba mi sọ̀rọ si tún de, o si ji mi, bi ọkunrin ti a ji lati oju orun rẹ̀,
2 O si wi fun mi pe, Kini iwọ ri? Mo si wipe, mo wò, si kiyesi i, ọ̀pa fitilà ti gbogbo rẹ̀ jẹ wurà, pẹlu kòjo rẹ̀ lori rẹ̀, pẹlu fitilà meje rẹ̀ lori rẹ̀, ati àrọ meje fun fitilà mejeje, ti o wà lori rẹ̀:
3 Igi olifi meji si wà leti rẹ̀, ọkan li apa ọtun kòjo na, ati ekeji li apa osì rẹ̀.
4 Mo si dahùn mo si wi fun angeli ti o mba mi sọ̀rọ, pe, Kini wọnyi, Oluwa mi?
5 Angeli ti o mba mi sọ̀rọ dahùn o si wi fun mi pe, Iwọ kò mọ̀ ohun ti awọn wọnyi jasi? Mo si wipe, Nkò mọ̀, oluwa mi.
6 O si dahùn o si wi fun mi pe, Eyi ni ọ̀rọ Oluwa si Serubbabeli wipe, Kì iṣe nipa ipá, kì iṣe nipa agbara, bikoṣe nipa Ẹmi mi, ni Oluwa awọn ọmọ-ogun wi.
7 Tani iwọ, Iwọ oke nla? iwọ o di pẹ̀tẹlẹ niwaju Serubbabeli: on o si fi ariwo mu okuta tenté ori rẹ̀ wá, yio ma kigbe wipe, Ore-ọfẹ, ore-ọfẹ si i.
8 Ọ̀rọ Oluwa si tọ̀ mi wá, wipe,
9 Ọwọ Serubbabeli li o pilẹ ile yi; ọwọ rẹ̀ ni yio si pari rẹ̀; iwọ o si mọ̀ pe, Oluwa awọn ọmọ-ogun li o rán mi si nyin.
10 Ṣugbọn tani ha kẹgàn ọjọ ohun kekere? nitori nwọn o yọ̀, nwọn o si ri iwọ̀n lọwọ Serubbabeli pẹlu meje wọnni; awọn ni oju Oluwa, ti o nsare sihin sọhun ni gbogbo aiye.
11 Mo si dahun, mo si sọ fun u pe, Kini awọn igi olifi meji wọnyi jasi, ti o wà li apá ọtun fitilà ati li apá osì rẹ̀?
12 Mo si tún dahùn, mo si sọ fun u pe, Kini awọn ẹka meji igi olifi wọnyi jasi, ti ntú ororo wurà jade lori wọn lati inu ikòko wurà.
13 O si dahùn, o wi fun mi pe, Iwọ kò mọ̀ ohun ti awọn wọnyi jasi? Mo si wipe, N kò mọ̀, oluwa mi.
14 O si wipe, Awọn meji wọnyi ni awọn ti a fi ororo yàn, ti o duro tì Oluwa gbogbo aiye.