1 LI ọjọ na isun kan yio ṣi silẹ fun ile Dafidi ati fun awọn ara Jerusalemu, fun ẹ̀ṣẹ ati fun ìwa aimọ́.
2 Yio si ṣe li ọjọ na, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, li emi o ke orukọ awọn òriṣa kuro ni ilẹ na, a kì yio si ranti wọn mọ: ati pẹlu emi o mu awọn woli ati awọn ẹmi aimọ́ kọja kuro ni ilẹ na.
3 Yio si ṣe, nigbati ẹnikan yio sọtẹlẹ sibẹ̀, ni baba rẹ̀ ati iya rẹ̀ ti o bi i yio wi fun u pe, Iwọ kì yio yè: nitori iwọ nsọ̀rọ eké li orukọ Oluwa: ati baba rẹ̀ ati iya rẹ̀ ti o bi i yio gún u li agúnyọ nigbati o ba sọ̀tẹlẹ.
4 Yio si ṣe li ọjọ na, oju yio tì awọn woli olukulukù nitori iran rẹ̀, nigbati on ba ti sọtẹlẹ; bẹ̃ni nwọn kì yio si wọ̀ aṣọ onirun lati tan ni jẹ:
5 Ṣugbọn on o wipe, Emi kì iṣe woli, agbẹ̀ li emi; nitori enia li o ni mi bi iranṣẹ lati igbà ewe mi wá.
6 Ẹnikan o si wi fun u pe, Ọgbẹ́ kini wọnyi li ọwọ rẹ? On o si dahùn pe, Wọnyi ni a ti ṣá mi ni ile awọn ọrẹ́ mi.
7 Dide, iwọ idà, si olùṣọ-agùtan mi, ati si ẹniti iṣe ẹnikeji mi, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi; kọlù olùṣọ-agùtan, awọn àgutan a si tuká: emi o si yi ọwọ mi si awọn kékèké.
8 Yio si ṣe, ni gbogbo ilẹ, li Oluwa wi, a o ké apá meji ninu rẹ̀ kuro yio si kú; ṣugbọn apá kẹta yio kù ninu rẹ̀.
9 Emi o si mu apá kẹta na là ãrin iná, emi o si yọ́ wọn bi a ti yọ́ fàdakà, emi o si dán wọn wò, bi a ti idán wura wò: nwọn o si pè orukọ mi, emi o si gbọ́ wọn: emi o wipe, Awọn enia mi ni: awọn o si wipe, Oluwa li Ọlọrun mi.