7 Gbogbo awọn ere fifin rẹ̀ ni a o run womu-womu, gbogbo awọn ẹbùn rẹ̀ li a o fi iná sun, gbogbo awọn oriṣà rẹ̀ li emi o sọ di ahoro: nitoriti o ko o jọ lati inu ẹbùn panṣaga wá, nwọn o si pada si ẹbùn panṣaga.
8 Nitori eyi li emi o ṣe pohunrere, ti emi o si ma hu, emi o ma lọ ni ẹsẹ lasan, ati ni ihòho: emi o pohunrere bi dragoni, emi o si ma kedaro bi awọn ọmọ ògongo.
9 Nitori ti ọgbẹ́ rẹ̀ jẹ alailewòtan; nitoriti o wá si Juda; on de ẹnu-bode awọn enia mi, ani si Jerusalemu.
10 Ẹ máṣe sọ ni Gati, ẹ máṣe sọkun rara: ni ile Afra mo yi ara mi ninu ekuru.
11 Ẹ kọja lọ, iwọ ará Safiri, pẹlu itiju rẹ ni ihòhò: ara Saanani kò jade wá; ọ̀fọ̀ Beteseli yio gba iduro rẹ̀ lọwọ nyin.
12 Nitori ara Maroti nreti ire, ṣugbọn ibi sọkalẹ ti ọdọ Oluwa wá si ẹnu bode Jerusalemu.
13 Iwọ ara Lakiṣi, di kẹkẹ mọ ẹranko ti o yara: on ni ibẹrẹ ẹ̀ṣẹ si ọmọbinrin Sioni: nitori a ri irekọja Israeli ninu rẹ.