Mik 5 YCE

1 NISISIYI gbá ara rẹ jọ li ọwọ́, Iwọ ọmọbinrin ọwọ́: o ti dó tì wa; nwọn o fi ọ̀pa lu onidajọ Israeli li ẹ̀rẹkẹ.

Ọlọrun Ṣèlérí láti Yan Olórí ní Bẹtlẹhẹmu

2 Ati iwọ Betlehemu Efrata; bi iwọ ti jẹ kekere lãrin awọn ẹgbẹgbẹ̀run Juda, ninu rẹ ni ẹniti yio jẹ olori ni Israeli yio ti jade tọ̀ mi wá; ijade lọ rẹ̀ si jẹ lati igbãni, lati aiyeraiye.

3 Nitorina ni yio ṣe jọwọ wọn lọwọ, titi di akokò ti ẹniti nrọbi yio fi bi: iyokù awọn arakunrin rẹ̀ yio si pada wá sọdọ awọn ọmọ Israeli.

4 On o si duro yio si ma jẹ̀ li agbara Oluwa, ni ọlanla orukọ Oluwa Ọlọrun rẹ̀; nwọn o si wà, nitori nisisiyi ni on o tobi titi de opin aiye.

5 Eleyi ni yio jẹ alafia, nigbati ara Assiria yio wá si ilẹ wa; nigbati yio si tẹ̀ awọn ãfin wa mọlẹ, nigba nã li awa o gbe oluṣọ agutan meje dide si i, ati olori enia mẹjọ.

Ìdásílẹ̀ ati Ìjìyà

6 Nwọn o si fi idà pa ilẹ Assiria run, ati ilẹ Nimrodu ni àbawọ̀ inu rẹ̀: yio si gbà wa lọwọ ara Assiria nigbati o ba wá ilẹ wa, ati nigbati o ba si ntẹ̀ àgbegbe wa mọlẹ.

7 Iyokù Jakobu yio si wà lãrin ọ̀pọ enia bi irì lati ọdọ Oluwa wá, bi ọwarà òjo lori koriko, ti kì idara duro de enia, ti kì isi duro de awọn ọmọ enia.

8 Iyokù Jakobu yio si wà lãrin awọn Keferi, lãrin ọ̀pọ enia bi kiniun, lãrin awọn ẹranko igbo, bi ọmọkiniun lãrin agbo agutan; eyiti, bi o ba là a ja, ti itẹ̀ mọlẹ, ti isi ifa ya pẹrẹpẹrẹ, kò si ẹniti yio gbalà.

9 A o gbe ọwọ́ rẹ soke sori awọn ọ̀ta rẹ, gbogbo awọn ọ̀ta rẹ, li a o si ke kuro.

10 Yio si ṣe li ọjọ na, ni Oluwa wi, ti emi o ke awọn ẹṣin rẹ kuro lãrin rẹ, emi o si pa awọn kẹkẹ́ ogun rẹ run.

11 Emi o si ke ilu-nla ilẹ rẹ kuro, emi o si tì gbogbo odi rẹ ṣubu:

12 Emi o si ke iwà-ajẹ kuro lọwọ rẹ: iwọ kì yio si ni alafọ̀ṣẹ mọ:

13 Ere fifin rẹ pẹlu li emi o ke kuro, awọn ere rẹ kuro lãrin rẹ; iwọ kì o si ma sin iṣẹ ọwọ́ rẹ mọ.

14 Emi o si tú igbo òriṣa rẹ kuro lãrin rẹ: emi o si pa awọn ilu rẹ run.

15 Emi o si gbẹsan ni ibinu ati irunu lara awọn keferi, ti nwọn kò ti igbọ́ ri.

orí

1 2 3 4 5 6 7