Mik 2 YCE

Ìjìyà fún Àwọn Tí Wọn ń Ni Àwọn Talaka Lára

1 EGBE ni fun awọn ti ngbìmọ aiṣedede, ti nṣiṣẹ ibi lori akete wọn! nigbati ojumọ́ mọ́ nwọn nṣe e, nitoripe o wà ni agbara ọwọ́ wọn.

2 Nwọn si nṣe ojukòkoro oko, nwọn si nfi ipá gbà a: ati ile, nwọn a si mu wọn lọ: nwọn si ni enia lara ati ile rẹ̀, ani enia ati ini rẹ̀.

3 Nitorina bayi ni Oluwa wi; Kiyesi i, emi ngbimọ̀ ibi si idile yi, ninu eyiti ọrùn nyin kì yio le yọ; bẹni ẹnyin kì yio fi igberaga lọ: nitori akokò ibi ni yi.

4 Li ọjọ na ni ẹnikan yio pa owe kan si nyin, yio si pohunrere-ẹkun kikorò pe, Ni kikó a kó wa tan? on ti pin iní enia mi: bawo ni o ti ṣe mu u kuro lọdọ mi! o ti pin oko wa fun awọn ti o yapa.

5 Nitorina iwọ kì yio ni ẹnikan ti yio ta okùn nipa ìbo ninu ijọ enia Oluwa.

6 Nwọn ni, ẹ máṣe sọtẹlẹ, nwọn o sọtẹlẹ, bi nwọn kò ba sọtẹlẹ bayi, itiju kì yio kuro.

7 Iwọ ẹniti anpe ni ile Jakobu, Ẹmi Oluwa ha bùkù bi? iṣe rẹ̀ ha ni wọnyi? ọ̀rọ mi kò ha nṣe rere fun ẹni ti nrin dẽde bi?

8 Ati nijelo awọn enia mi dide bi ọta si mi: ẹnyin ti bọ́ ẹ̀wu ati aṣọ ibora kuro lọdọ awọn ti nkọja li ailewu, bi awọn ẹniti o kọ̀ ogun silẹ.

9 Obinrin awọn enia mi li ẹnyin ti le jade kuro ninu ile wọn daradara; ẹnyin ti gbà ogo mi kuro lọwọ awọn ọmọ wọn lailai.

10 Ẹ dide, ki ẹ si ma lọ; nitoripe eyi kì iṣe ibi isimi: nitoriti o jẹ alaimọ́, yio pa nyin run, ani iparun kikorò?

11 Bi enia kan ti nrin ninu ẹmi ati itanjẹ ba ṣeke, wipe, emi o sọ asọtẹlẹ̀ ti ọti-waini ati ọti-lile fun ọ; on ni o tilẹ ṣe woli awọn enia yi.

12 Ni kikó emi o kó nyin jọ, iwọ Jakobu, gbogbo nyin; ni gbigbá emi o gbá iyokù Israeli jọ; emi o si tò wọn jọ pọ̀ gẹgẹ bi agutan Bosra, gẹgẹ bi ọwọ́ ẹran ninu agbo wọn: nwọn o si pariwo nla nitori ọ̀pọlọpọ enia.

13 Ẹniti nfọ́ni ti dide niwaju wọn: nwọn ti fọ́, nwọn kọja lãrin bode, nwọn si ti jade lọ nipa rẹ̀: ọba wọn o si kọja lọ niwaju wọn, Oluwa ni yio si ṣe olori wọn.

orí

1 2 3 4 5 6 7