1 Ẹ gbọ́ nisisiyi ohun ti Oluwa wi; Dide, ba oke nla wijọ, si jẹ ki oke kékèké gbohùn rẹ.
2 Ẹ gbọ́ ẹjọ Oluwa, ẹnyin oke-nla, ati ẹnyin ipilẹ ilẹ̀ aiye: nitori Oluwa mba awọn enia rẹ̀ wijọ, yio si ba Israeli rojọ.
3 Enia mi, kini mo fi ṣe ọ? ati ninu kini mo fi da ọ li agara? dahùn si i.
4 Nitori mo ti mu ọ goke lati ilẹ Egipti wá, mo si rà ọ padà lati ile ẹrú wá; mo si rán Mose, Aaroni, ati Miriamu siwaju rẹ.