4 Nitori mo ti mu ọ goke lati ilẹ Egipti wá, mo si rà ọ padà lati ile ẹrú wá; mo si rán Mose, Aaroni, ati Miriamu siwaju rẹ.
5 Enia mi, ranti nisisiyi ohun ti Balaki ọba Moabu gbèro, ati ohun ti Balaamu ọmọ Beori dá a lohùn lati Ṣittimu titi de Gilgali; ki ẹ ba le mọ̀ ododo Oluwa.
6 Kini emi o ha mu wá siwaju Oluwa, ti emi o fi tẹ̀ ara mi ba niwaju Ọlọrun giga? ki emi ha wá siwaju rẹ̀ pẹlu ọrẹ-ẹbọ sisun, pẹlu ọmọ malu ọlọdún kan?
7 Inu Oluwa yio ha dùn si ẹgbẹgbẹ̀run àgbo, tabi si ẹgbẹgbãrun iṣàn òroro? emi o ha fi àkọbi mi fun irekọja mi, iru-ọmọ inu mi fun ẹ̀ṣẹ ọkàn mi?
8 A ti fi hàn ọ, Iwọ enia, ohun ti o dara; ati ohun ti Oluwa bère lọwọ rẹ, bikoṣe ki o ṣe otitọ, ki o si fẹ ãnu, ati ki o rìn ni irẹ̀lẹ pẹlu Ọlọrun rẹ?
9 Ohùn Oluwa kigbe si ilu na, ọlọgbọ́n yio si ri orukọ rẹ; ẹ gbọ́ ọ̀pa na, ati ẹniti o yàn a?
10 Iṣura ìwa buburu ha wà ni ile enia buburu sibẹ̀, ati òṣuwọ̀n aikún ti o jẹ ohun ibinú?