7 Nitorina emi o ni ireti si Oluwa: emi o duro de Ọlọrun igbala mi: Ọlọrun mi yio gbọ́ temi.
8 Má yọ̀ mi, Iwọ ọta mi: nigbati mo ba ṣubu, emi o dide; nigbati mo ba joko li okùnkun, Oluwa yio jẹ imọlẹ fun mi.
9 Emi o rù ibinu Oluwa, nitori emi ti dẹṣẹ si i, titi yio fi gbà ẹjọ mi rò, ti yio si ṣe idajọ mi; yio mu mi wá si imọlẹ, emi o si ri ododo rẹ̀.
10 Nitori ọta mi yio ri i, itiju yio si bò ẹniti o wipe, Nibo ni Oluwa Ọlọrun rẹ wà? oju mi yio ri i, nisisiyi ni yio di itẹ̀mọlẹ bi ẹrẹ̀ ita.
11 Ọjọ ti a o mọ odi rẹ, ọjọ na ni aṣẹ yio jinà rére.
12 Ọjọ na ni nwọn o si ti Assiria wá sọdọ rẹ, ati lati ilu olodi, ati lati ile iṣọ́ alagbara titi de odò, ati lati okun de okun, ati oke-nla de oke-nla.
13 Ilẹ na yio si di ahoro fun awọn ti ngbe inu rẹ̀, nitori eso ìwa wọn.