O. Sol 2 YCE

1 EMI ni itanná eweko Ṣaroni, ati itanná lili awọn afonifoji.

2 Bi itanná lili lãrin ẹgún, bẹ̃li olufẹ mi ri lãrin awọn ọmọbinrin.

3 Bi igi eleso lãrin awọn igi igbẹ, bẹ̃li olufẹ mi ri lãrin awọn ọmọkunrin. Emi fi ayọ̀ nla joko labẹ ojiji rẹ̀, eso rẹ̀ si dùn mọ mi li ẹnu.

4 O mu mi wá si ile ọti-waini, Ifẹ si ni ọpagun rẹ̀ lori mi.

5 Fi akara didùn da mi duro, fi eso igi tù mi ni inu: nitori aisàn ifẹ nṣe mi.

6 Ọwọ osì rẹ̀ mbẹ labẹ ori mi, ọwọ ọtún rẹ̀ si gbá mi mọra.

7 Mo fi awọn abo egbin, ati awọn abo agbọnrin igbẹ fi nyin bú, ẹnyin ọmọbinrin Jerusalemu, ki ẹ máṣe rú olufẹ mi soke, ki ẹ má si ṣe ji i, titi yio fi wù u.

8 Ohùn olufẹ mi! sa wò o, o mbọ̀, o nfò lori awọn òke, o mbẹ lori awọn òke kékeké.

9 Olufẹ mi dabi abo egbin, tabi ọmọ agbọnrin: sa wò o, o duro lẹhin ogiri wa, o yọju loju ferese, o nfi ara rẹ̀ hàn loju ferese ọlọnà.

10 Olufẹ mi sọ̀rọ, o si wi fun mi pe, Dide, olufẹ mi, arẹwà mi kanna, ki o si jade kalọ.

11 Sa wò o, ìgba otutu ti kọja, òjo ti da, o si ti lọ.

12 Awọn itanna eweko farahàn lori ilẹ; akoko ikọrin awọn ẹiyẹ de, a si gbọ ohùn àdaba ni ilẹ wa.

13 Igi ọ̀pọtọ so eso titun, awọn àjara funni ni õrun daradara nipa itanná wọn. Dide, olufẹ mi, arẹwà mi kanna, ki o si jade kalọ.

14 Adaba mi, ti o wà ninu pàlapala okuta, ni ibi ìkọkọ okuta, jẹ ki emi ri oju rẹ, jẹ ki emi gbọ́ ohùn rẹ; nitori didùn ni ohùn rẹ, oju rẹ si li ẹwà.

15 Mu awọn kọ̀lọkọlọ fun wa, awọn kọ̀lọkọlọ kékeké ti mba àjara jẹ: nitori àjara wa ni itanná.

16 Olufẹ mi ni temi, emi si ni tirẹ̀: o njẹ lãrin awọn lili.

17 Titi ìgba itura ọjọ, titi ojiji yio fi salọ, yipada, olufẹ mi, ki iwọ ki o si dabi abo egbin, tabi ọmọ agbọnrin lori awọn oke Beteri.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8