O. Sol 8 YCE

1 IWỌ iba jẹ dabi arakunrin fun mi, ti o mu ọmú iya mi! emi iba ri ọ lode emi iba fi ẹnu kò ọ lẹnu; lõtọ, nwọn kì ba fi mi ṣe ẹlẹya.

2 Emi iba fọnahàn ọ, emi iba mu ọ wá sinu ile iya mi, iwọ iba kọ́ mi: emi iba mu ọ mu ọti-waini õrùn didùn, ati oje eso granate mi.

3 Ọwọ osì rẹ̀ iba wà labẹ ori mi, ọwọ ọtún rẹ̀ iba si gbá mi mọra.

4 Mo fi nyin bu, ẹnyin ọmọbinrin Jerusalemu, ki ẹ máṣe rú olufẹ mi soke, ki ẹ má si ṣe ji i, titi yio fi wù u.

5 Tani eyi ti ngòke lati aginju wá, ti o fi ara tì olufẹ rẹ̀? mo ji ọ dide labẹ igi eleso: nibẹ ni iya rẹ gbe bi ọ si, nibẹ li ẹniti o bi ọ gbe bi ọ si.

6 Gbe mi ka aiya rẹ bi edidi, bi edidi le apá rẹ: nitori ifẹ lagbara bi ikú; ijowu si le bi isa-okú; jijo rẹ̀ dabi jijo iná, ani ọwọ iná Oluwa.

7 Omi pupọ kò le paná ifẹ, bẹ̃ni kikún omi kò le gbá a lọ, bi enia fẹ fi gbogbo ọrọ̀ rẹ̀ fun ifẹ, a o kẹgàn rẹ̀ patapata.

8 Awa ni arabinrin kekere kan, on kò si ni ọmú: kili awa o ṣe fun arabinrin wa li ọjọ ti a o ba fẹ ẹ?

9 Bi on ba ṣe ogiri, awa o kọ́ ile-odi fadaka le e lori: bi on ba si ṣe ẹnu-ọ̀na, awa o fi apako kedari dí i.

10 Ogiri ni mi, ọmú mi sì dabi ile-iṣọ: nigbana loju rẹ̀ mo dabi ẹniti o ri alafia.

11 Solomoni ni ọgba-àjara kan ni Baalhamoni; o fi ọgba-àjara na ṣe ọ̀ya fun awọn oluṣọ; olukuluku ni imu ẹgbẹrun fadaka wá nipò eso rẹ̀.

12 Ọgba-àjara mi, ti iṣe temi, o wà niwaju mi: iwọ Solomoni yio ni ẹgbẹrun fadaka, ati awọn ti nṣọ eso na yio ni igba.

13 Iwọ ti ngbe inu ọgbà, awọn ẹgbẹ rẹ fetisi ohùn rẹ: mu mi gbọ́ ọ pẹlu.

14 Yara, olufẹ mi, ki iwọ ki o si dabi abo egbin tabi ọmọ agbọnrin lori òke õrùn didùn.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8