1 IRAN Isaiah ọmọ Amosi, ti o rí nipa Juda ati Jerusalemu li ọjọ Ussiah, Jotamu, Ahasi, ati Hesekiah, awọn ọba Juda.
2 Gbọ́, ẹnyin ọrun, si fi eti silẹ, iwọ aiye: nitori Oluwa ti sọ̀rọ, emi ti bọ́, emi si ti tọ́ awọn ọmọ, nwọn si ti ṣọ̀tẹ si mi.
3 Malũ mọ̀ oluwa rẹ̀, kẹtẹ́kẹtẹ si mọ̀ ibujẹ oluwa rẹ̀: ṣugbọn Israeli kò mọ̀, awọn enia mi kò ronu.
4 A! orilẹ-ède ti o kún fun ẹ̀ṣẹ, enia ti ẹrù ẹ̀ṣẹ npa, irú awọn oluṣe buburu, awọn ọmọ ti iṣe olubajẹ: nwọn ti kọ̀ Oluwa silẹ, nwọn ti mu Ẹni-Mimọ́ Israeli binu, nwọn si ti yipada sẹhìn.
5 Ẽṣe ti a o fi lù nyin si i mọ? ẹnyin o ma ṣọ̀tẹ siwaju ati siwaju: gbogbo ori li o ṣaisàn, gbogbo ọkàn li o si dakú.
6 Lati atẹlẹ̀sẹ titi fi de ori kò si ilera ninu rẹ̀; bikòṣe ọgbẹ́, ipalara, ati õju ti nrà: nwọn kò iti pajumọ, bẹ̃ni a kò iti dì wọn, bẹ̃ni a kò si ti ifi ororo kùn wọn.
7 Ilẹ nyin di ahoro, a fi iná kun ilu nyin: ilẹ nyin, alejo jẹ ẹ run li oju nyin, o si di ahoro, bi eyiti awọn alejo wó palẹ.
8 Ọmọbinrin Sioni li a si fi silẹ bi agọ ninu ọgbà àjara, bi abule ninu ọgbà ẹ̀gúsí, bi ilu ti a dóti.
9 Bikòṣe bi Oluwa awọn ọmọ-ogun ti fi iyokù diẹ kiun silẹ fun wa, awa iba ti dabi Sodomu, awa iba si ti dabi Gomorra.
10 Gbọ́ ọ̀rọ Oluwa, ẹnyin olori Sodomu; fi eti si ofin Ọlọrun wa, ẹnyin enia Gomorra.
11 Oluwa ni, kini ọ̀pọlọpọ ẹbọ nyin jasi fun mi? emi kún fun ọrẹ sisun agbò, ati fun ọrá ẹran abọ́pa; bẹ̃ni emi kò si ni inu didùn si ẹjẹ akọ malũ, tabi si ti ọdọ-agutan, tabi si ti obúkọ.
12 Nigbati ẹnyin wá lati fi ara hàn niwaju mi, tali o bere eyi lọwọ nyin, lati tẹ̀ agbalá mi?
13 Ẹ má mu ọrẹ asan wá mọ́: turari jasi ohun irira fun mi; oṣù titun ati ọjọ isimi, ìpe ajọ, emi kò le rọju gbà; ẹ̀ṣẹ ni, ani apèjọ ọ̀wọ nì.
14 Oṣù titun nyin ati ajọ ìdasilẹ nyin, ọkàn mi korira; nwọn jasi iyọlẹnu fun mi; o sú mi lati gbà wọn.
15 Nigbati ẹnyin si nà ọwọ́ nyin jade, emi o pa oju mi mọ fun nyin: nitõtọ, nigbati ẹnyin ba gbà adura pupọ, emi kì yio gbọ́: ọwọ́ nyin kún fun ẹ̀jẹ.
16 Ẹ wẹ̀, ki ẹ mọ́; mu buburu iṣe nyin kuro niwaju oju mi: dawọ duro lati ṣe buburu;
17 Kọ́ lati ṣe rere; wá idajọ, ràn awọn ẹniti a nilara lọwọ, ṣe idajọ alainibaba, gbà ẹjọ opó rò.
18 Oluwa wipe, wá nisisiyi, ki ẹ si jẹ ki a sọ asọyé pọ̀: bi ẹ̀ṣẹ nyin ba ri bi òdodó, nwọn o si fun bi òjo-didì; bi nwọn pọ́n bi àlãri, nwọn o dabi irun-agutan.
19 Bi ẹnyin ba fẹ́ ti ẹ si gbọran, ẹnyin o jẹ ire ilẹ na:
20 Ṣugbọn bi ẹnyin ba kọ̀, ti ẹ si ṣọ̀tẹ, a o fi idà run nyin: nitori ẹnu Oluwa li o ti wi i.
21 Ilu otitọ ha ti ṣe di àgbere! o ti kún fun idajọ ri; ododo ti gbe inu rẹ̀ ri; ṣugbọn nisisiyi, awọn apania.
22 Fadaka rẹ ti di ìdarọ́, ọti-waini rẹ ti dà lu omi:
23 Awọn ọmọ-alade rẹ di ọlọ̀tẹ, ati ẹgbẹ olè: olukuluku nfẹ́ ọrẹ, o si ntọ̀ erè lẹhin: nwọn kò ṣe idajọ alainibaba, bẹ̃ni ọ̀ran opó kò wá sọdọ wọn.
24 Nitorina Oluwa, Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ẹni alagbara Israeli, wipe, A, emi o fi aiya balẹ niti awọn ọtá mi, emi o si gbẹ̀san lara awọn ọtá mi.
25 Emi o yi ọwọ́ mi si ara rẹ, emi o si yọ́ ìdarọ́ rẹ kuro patapata, emi o si mu gbogbo tanganran rẹ kuro:
26 Emi o si mu awọn onidajọ rẹ pada bi igbà iṣãju, ati awọn igbìmọ rẹ bi igbà akọbẹ̀rẹ: lẹhin na, a o pè ọ ni, Ilu ododo, ilu otitọ.
27 Idajọ li a o fi rà Sioni pada, ati awọn ti o pada bọ̀ nipa ododo.
28 Iparun awọn alarekọja pẹlu awọn ẹlẹṣẹ yio wà pọ̀, ati awọn ti o kọ̀ Oluwa silẹ li a o parun.
29 Nitoriti oju yio tì wọn niti igi-nla ti ẹnyin ti fẹ, a o si dãmu nyin niti ọgbà ti ẹnyin ti yàn.
30 Nitori ẹnyin o dabi igi-nla ti ewe rẹ̀ rọ, ati bi ọgbà ti kò ni omi.
31 Alagbara yio si dabi ògùṣọ̀, iṣẹ rẹ̀ yio si dabi ẹta-iná, ati awọn mejeji yio jọ jona pọ̀, ẹnikẹni kì yio si pa wọn.