Isa 21 YCE

Ìran nípa Ìṣubú Babiloni

1 Ọ̀RỌ-ìmọ niti ijù okun. Gẹgẹ bi ãja gusù ti ikọja lọ; bẹ̃ni o ti ijù wá, lati ilẹ ti o li ẹ̀ru.

2 Iran lile li a fi hàn mi; ọ̀dalẹ dalẹ, akoni si nkoni. Goke lọ, iwọ Elamu: dotì, iwọ Media; gbogbo ìmí-ẹ̀dùn inu rẹ̀ li emi ti mu da.

3 Nitorina ni ẹgbẹ́ mi ṣe kun fun irora: irora si ti dì mi mu, gẹgẹ bi irora obinrin ti nrọbi: emi tẹ̀ ba nigbati emi gbọ́ ọ: emi dãmu nigbati emi ri i.

4 Ọkàn mi nrò, ẹ̀ru dẹrùba mi: oru ayọ̀ mi li o ti sọ di ìbẹru fun mi.

5 Pèse tabili silẹ, yàn alore, jẹ, mu: dide, ẹnyin ọmọ-alade, ẹ kùn asà nyin.

6 Nitori bayi li Oluwa ti sọ fun mi, Lọ, fi ẹnikan ṣọ ọ̀na, jẹ ki o sọ ohun ti o ri.

7 O si ri kẹkẹ́ pẹlu ẹlẹṣin meji-meji, kẹkẹ́ kẹtẹkẹtẹ, kẹkẹ́ ibakasiẹ; o si farabalẹ̀ tẹtilelẹ gidigidi:

8 On si kigbe pe, kiniun kan: Oluwa mi, nigbagbogbo li emi nduro lori ile-iṣọ li ọsan, a si fi mi si iṣọ mi ni gbogbo oru:

9 Si kiyesi i, kẹkẹ́ enia kan ni mbọ̀ wá yi, pẹlu ẹlẹṣin meji-meji. On si dahun, o si wipe, Babiloni ṣubu, o ṣubu; ati gbogbo ere fifin òriṣa rẹ̀ li o wó mọlẹ.

10 Iwọ ìpaka mi, ati ọkà ilẹ ìpaka mi: eyi ti emi ti gbọ́ lọdọ Oluwa awọn ọmọ-ọgun, Ọlọrun Israeli li emi ti sọ fun ọ.

Àsọtẹ́lẹ̀ nípa Edomu

11 Ọ̀rọ-ìmọ niti Duma. O ké si mi lati Seiri wá, Oluṣọ́, oru ti ri? Oluṣọ́ oru ti ri?

12 Oluṣọ́ wipe, ilẹ nmọ́ bọ̀, alẹ si nlẹ pẹlu: bi ẹnyin o ba bere, ẹ bere: ẹ pada, ẹ wá.

Àsọtẹ́lẹ̀ nípa Arabia

13 Ọ̀rọ-ìmọ niti Arabia. Ninu igbó Arabia li ẹnyin o wọ̀, ẹnyin ẹgbẹ́-erò Dedanimu.

14 Awọn olugbé ilẹ Tema bù omi wá fun ẹniti ongbẹ ngbẹ, onjẹ wọn ni nwọn fi ṣaju ẹniti nsalọ.

15 Nitori nwọn nsá fun idà, fun idà fifayọ, ati fun ọrun kikàn, ati fun ibinujẹ ogun.

16 Nitori bayi li Oluwa ti sọ fun mi, ki ọdun kan to pe, gẹgẹ bi ọdun alagbaṣe, gbogbo ogo Kedari yio wọ̀.

17 Iyokù ninu iye awọn tafàtafà, awọn alagbara ninu awọn ọmọ Kedari yio dinkù: nitori Oluwa Ọlọrun Israeli ti wi i.