Isa 29 YCE

Òkè Sioni Ìlú Dafidi

1 EGBE ni fun Arieli, fun Arieli, ilu ti Dafidi ti ngbe! ẹ fi ọdun kún ọdun; jẹ ki wọn pa ẹran rubọ.

2 Ṣugbọn emi o pọ́n Arieli loju, àwẹ on ibanujẹ yio si wà; yio si dabi Arieli si mi.

3 Emi o si dótì ọ yika, emi o si wà odi tì ọ, emi o si mọ odi giga tì ọ.

4 A o si rẹ̀ ọ silẹ, iwọ o sọ̀rọ lati ilẹ jade, ọ̀rọ rẹ yio rẹ̀lẹ lati inu ekuru wá, ohùn rẹ yio si dabi ti ẹnikan ti o li ẹmi àfọṣẹ lati ilẹ jade, ọ̀rọ rẹ yio si dún lati inu erupẹ ilẹ wá.

5 Ọpọlọpọ awọn ọtá rẹ yio dabi ekuru lẹ́bulẹ́bu, ọpọlọpọ aninilara rẹ yio dabi ìyangbo ti o kọja lọ: lõtọ, yio ri bẹ̃ nisisiyi lojiji.

6 Ãrá, ìṣẹlẹ, ati iró nla, pẹlu ìji on ẹfúfu, ati ọwọ́ ajonirun iná ni a o fi bẹ̀ ọ wò lati ọdọ Oluwa awọn ọmọ-ogun wá.

7 Bi alá iran oru li ọ̀pọlọpọ awọn orilẹ-ède ti mba Arieli jà yio ri; gbogbo ẹniti o bá ati on, ati odi agbara rẹ̀ jà, ti nwọn si pọ́n ọ loju.

8 Yio si dabi igbati ẹni ebi npa nla alá; si wo o, o njẹun; ṣugbọn o ji, ọkàn rẹ̀ si ṣofo: tabi bi igbati ẹniti ongbẹ ngbẹ nla alá, si wo o, o nmu omi, ṣugbọn o ji, si wo o, o dáku, ongbẹ si ngbẹ ọkàn rẹ̀; gẹgẹ bẹ̃ ni gbogbo ọ̀pọlọpọ orilẹ-ède yio ri, ti mba oke Sioni jà.

Ìkìlọ̀ tí A kò Náání

9 Mu ara duro jẹ, ki ẹnu ki o yà nyin; ẹ fọ́ ara nyin loju, ẹ si fọju: nwọn mu amupara; ṣugbọn kì iṣe fun ọti-waini, nwọn nta gbọngbọ́n ṣugbọn kì iṣe fun ohun mimu lile.

10 Nitori Oluwa dà ẹmi õrun ijìka lù nyin, o si se nyin li oju: awọn wolĩ ati awọn olori awọn ariran nyin li o bò li oju.

11 Iran gbogbo si dabi ọ̀rọ iwe kan fun nyin ti a dí, ti a fi fun ẹnikan ti o mọ̀ ọ kà, wipe, Emi bẹ̀ ọ, kà eyi, ti o si wipe, emi kò le ṣe e; nitori a ti dí i.

12 A si fi iwe na fun ẹniti kò mọ̀ iwe, wipe, Emi bẹ̀ ọ, kà eyi, on si wipe, emi kò mọ̀ iwe.

13 Nitorina Oluwa wipe, Niwọ̀n bi awọn enia yi ti nfi ẹnu wọn fà mọ mi, ti nwọn si nfi etè wọn yìn mi, ṣugbọn ti ọkàn wọn jìna si mi, ti nwọn si bẹru mi nipa ilana enia ti a kọ́ wọn.

14 Nitorina, Kiye si i, emi o ma ṣe iṣẹ́ iyanu lọ lãrin awọn enia yi, ani iṣẹ iyanu ati ajeji: ọgbọ́n awọn ọlọgbọ́n wọn yio si ṣegbe, oye awọn amoye wọn yio si põra.

15 Egbe ni fun awọn ti nwá ọ̀na lati fi ipinnu buruburu wọn pamọ́ kuro loju Oluwa, ti iṣẹ wọn si wà li okunkun, ti nwọn si wipe, Tali o ri wa? tali o mọ̀ wa?

Ìrètí Ọjọ́ Ọ̀la

16 A, iyipo nyin! a ha le kà amọ̀koko si bi amọ̀: ohun ti a mọ ti ṣe lè wi fun ẹniti o ṣe e pe, On kò ṣe mi? ìkoko ti a mọ le wi fun ẹniti o mọ ọ pe, On kò moye?

17 Kò ha ṣe pe ìgba diẹ kiun si i, a o sọ Lebanoni di ọgbà eleso, ati ọgbà eleso li a o kà si bi igbo?

18 Ati li ọjọ na awọn aditi yio si gbọ́ ọ̀rọ iwe nì, awọn afọju yio si riran lati inu owúsuwusù, ati lati inu okunkun.

19 Ayọ̀ awọn onirẹlẹ yio bí si i ninu Oluwa, ati inu awọn talaka ninu awọn enia yio si dùn ninu Ẹni-Mimọ Israeli.

20 Nitori a sọ aninilara na di asan, a si pa ẹlẹgàn run, a si ké gbogbo awọn ti nṣọ́ aiṣedede kuro.

21 Ẹniti o dá enia li ẹbi nitori ọ̀rọ kan, ti nwọn dẹkùn silẹ fun ẹniti o baniwi ni ẹnubodè, ti nwọn si tì olododo si apakan, si ibi ofo.

22 Nitorina bayi li Oluwa, ẹniti o rà Abrahamu padà wi, pe, niti ile Jakobu, oju kì yio tì Jakobu mọ bẹ̃ni oju rẹ̀ kì yio yipada mọ.

23 Ṣugbọn nigbati on nri awọn ọmọ rẹ̀, iṣẹ́ ọwọ́ mi, li ãrin rẹ̀, nwọn o yà orukọ mi si mimọ́, nwọn o si yà Ẹni-Mimọ Jakobu nì si mimọ́, nwọn o si bẹ̀ru Ọlọrun Israeli.

24 Awọn pẹlu ti o ṣinà nipa ẹmi, oye yio wá yé wọn, ati awọn ti nsọ bótibòti yio kọ́ ẹkọ́.