Isa 61 YCE

Ìròyìn Ayọ̀ Ìdáǹdè

1 ẸMI Oluwa Jehofah mbẹ lara mi: nitori o ti fi ami ororo yàn mi lati wãsu ihin-rere fun awọn òtoṣi; o ti rán mi lati ṣe awotán awọn onirobinujẹ ọkàn, lati kede idasilẹ fun awọn igbekùn, ati iṣisilẹ tubu fun awọn ondè.

2 Lati kede ọdun itẹwọgba Oluwa, ati ọjọ ẹsan Ọlọrun wa; lati tù gbogbo awọn ti ngbãwẹ̀ ninu.

3 Lati yàn fun awọn ti nṣọ̀fọ fun Sioni, lati fi ọṣọ́ fun wọn nipo ẽrú, ororo ayọ̀ nipo ọ̀fọ, aṣọ iyìn nipo ẹmi ibanujẹ, ki a le pè wọn ni igi ododo, ọgbìn Oluwa, ki a le yìn i logo.

4 Nwọn o si mọ ibi ahoro atijọ wọnni, nwọn o gbe ahoro atijọ wọnni ro, nwọn o si tun ilu wọnni ti o ṣofo ṣe, ahoro iran ọ̀pọlọpọ.

5 Awọn alejò yio si duro, nwọn o si bọ́ ọwọ́ ẹran nyin, awọn ọmọ alejò yio si ṣe atulẹ nyin, ati olurẹ́ ọwọ́ àjara nyin.

6 Ṣugbọn a o ma pè nyin ni Alufa Oluwa: nwọn o ma pè nyin ni Iranṣẹ Ọlọrun wa: ẹ o jẹ ọrọ̀ wọn Keferi, ati ninu ogo awọn li ẹ o mã ṣogo.

7 Nipo itijú nyin ẹ o ni iṣẹpo-meji; ati nipo idãmu, nwọn o yọ̀ ninu ipin wọn: nitorina nwọn o ni iṣẹpo-meji ni ilẹ wọn: ayọ̀ ainipẹkun yio jẹ ti wọn.

8 Nitori emi Oluwa fẹ idajọ, mo korira ijale ninu aiṣododo; emi o si fi iṣẹ wọn fun wọn ni otitọ, emi o si ba wọn da majẹmu aiyeraiye.

9 A o si mọ̀ iru wọn ninu awọn Keferi, ati iru-ọmọ wọn lãrin awọn enia, gbogbo ẹniti o ri wọn yio mọ̀ wọn, pé, iru-ọmọ ti Oluwa busi ni nwọn.

10 Emi o yọ̀ gidigidi ninu Oluwa, ọkàn mi yio yọ̀ ninu Ọlọrun mi; nitori o ti fi agbáda wọ̀ mi, o ti fi aṣọ ododo bò mi, gẹgẹ bi ọkọ iyawó ti iṣe ara rẹ̀ lọṣọ́, ati bi iyawó ti ifi ohun ọṣọ́ ṣe ara rẹ̀ lọṣọ́.

11 Nitori gẹgẹ bi ilẹ ti imu ẽhù rẹ̀ jade, ati bi ọgbà ti imu ohun ti a gbìn sinu rẹ̀ hù soke; bẹ̃ni Oluwa Jehofah yio mu ododo ati iyìn hù soke niwaju gbogbo orilẹ-ède.