Isa 43 YCE

OLUWA Ṣe Ìlérí láti Gba Àwọn Eniyan Rẹ̀ Là

1 ṢUGBỌN nisisiyi bayi ni Oluwa wi, ẹniti o dá ọ, Jakobu, ati ẹniti o mọ ọ, Israeli, Má bẹru: nitori mo ti rà ọ pada, mo ti pè ọ li orukọ rẹ, ti emi ni iwọ.

2 Nigbati iwọ ba nlà omi kọja, emi o pẹlu rẹ; ati lãrin odò, nwọn ki yio bò ọ mọlẹ: nigbati iwọ ba nrìn ninu iná, ki yio jo ọ, bẹ̃ni ọwọ́-iná ki yio ràn ọ.

3 Nitori emi li Oluwa Ọlọrun rẹ, Ẹni-Mimọ Israeli, Olugbala rẹ: mo fi Egipti ṣe irapada rẹ, mo si fi Etiopia ati Seba fun ọ.

4 Niwọn bi iwọ ti ṣe iyebiye to loju mi, ti iwọ ṣe ọlọla, emi si ti fẹ ọ: nitorina emi o fi enia rọpò rẹ, ati enia dipo ẹmi rẹ.

5 Má bẹ̀ru: nitori emi wà pẹlu rẹ; emi o mu iru-ọmọ rẹ lati ìla-õrun wá, emi o si ṣà ọ jọ lati ìwọ-õrun wá.

6 Emi o wi fun ariwa pe, Da silẹ; ati fun gusu pe, Máṣe da duro; mu awọn ọmọ mi ọkunrin lati okere wá, ati awọn ọmọ mi obinrin lati opin ilẹ wá.

7 Olukuluku ẹniti a npè li orukọ mi: nitori mo ti dá a fun ogo mi, mo ti mọ ọ, ani, mo ti ṣe e pé.

Ẹlẹ́rìí OLUWA ni Israẹli

8 Mu awọn afọju enia ti o li oju jade wá, ati awọn aditi ti o li eti.

9 Jẹ ki gbogbo awọn orilẹ-ède ṣa ara wọn jọ pọ̀, ki awọn enia pejọ; tani ninu wọn ti o le sọ eyi, ti o si le fi ohun atijọ han ni? jẹ ki wọn mu awọn ẹlẹri wọn jade, ki a le dá wọn lare; nwọn o si gbọ́, nwọn o si wipe, Õtọ ni.

10 Ẹnyin li ẹlẹri mi, ni Oluwa wi, ati iranṣẹ mi ti mo ti yàn: ki ẹnyin ki o le mọ̀, ki ẹ si gbà mi gbọ́ ki o si ye nyin pe, Emi ni; a kò mọ̀ Ọlọrun kan ṣãju mi, bẹ̃ni ọkan kì yio si hù lẹhin mi.

11 Emi, ani emi ni Oluwa; ati lẹhin mi, kò si olugbala kan.

12 Emi ti sọ, mo ti gbalà, mo si ti fi hàn, nigbati ko si ajeji ọlọrun kan lãrin nyin: ẹnyin ni iṣe ẹlẹri mi, li Oluwa wi, pe, Emi li Ọlọrun.

13 Lõtọ, ki ọjọ ki o to wà, Emi na ni, ko si si ẹniti o le gbani kuro li ọwọ́ mi: emi o ṣiṣẹ, tani o le yi i pada?

Sísá kúrò ní Babiloni

14 Bayi li Oluwa, olurapada nyin, Ẹni-Mimọ Israeli wi; Nitori nyin ni mo ṣe ranṣẹ si Babiloni, ti mo si jù gbogbo wọn bi isansa, ati awọn ara Kaldea, sisalẹ si awọn ọkọ̀ igbe-ayọ̀ wọn.

15 Emi ni Oluwa, Ẹni-Mimọ́ nyin, ẹlẹda Israeli Ọba nyin.

16 Bayi li Oluwa wi, ẹniti o la ọ̀na ninu okun, ati ipa-ọ̀na ninu alagbara omi;

17 Ẹniti o mu kẹkẹ ati ẹṣin jade, ogun ati agbara; nwọn o jumọ dubulẹ, nwọn kì yio dide: nwọn run, a pa wọn bi owú fitila.

18 Ẹ máṣe ranti nkan ti iṣaju mọ, ati nkan ti atijọ, ẹ máṣe rò wọn.

19 Kiyesi i, emi o ṣe ohun titun kan; nisisiyi ni yio hù jade; ẹnyin ki yio mọ̀ ọ bi? lõtọ, emi o là ọ̀na kan ninu aginju, ati odò li aṣalẹ̀.

20 Awọn ẹran igbẹ yio yìn mi logo, awọn dragoni ati awọn owiwi; nitori emi o funni li omi li aginjù, ati odo ni aṣalẹ̀, lati fi ohun mimu fun awọn enia mi, ayanfẹ mi;

21 Awọn enia yi ni mo ti mọ fun ara mi; nwọn o fi iyìn mi hàn.

Ẹ̀ṣẹ̀ Israẹli

22 Ṣugbọn iwọ kò ké pe mi, Jakobu; ṣugbọn ãrẹ̀ mu ọ nitori mi, iwọ Israeli.

23 Iwọ ko mu ọmọ-ẹran ẹbọ sisun rẹ fun mi wá; bẹ̃ni iwọ ko fi ẹbọ rẹ bu ọlá fun mi. Emi ko fi ọrẹ mu ọ sìn, emi ko si fi turari da ọ li agara.

24 Iwọ ko fi owo rà kalamu olõrun didun fun mi, bẹ̃ni iwọ ko fi ọra ẹbọ rẹ yó mi; ṣugbọn iwọ fi ẹ̀ṣẹ rẹ mu mi ṣe lãla, iwọ si fi aiṣedẽde rẹ da mi li agara.

25 Emi, ani emi li ẹniti o pa irekọja rẹ rẹ́ nitori ti emi tikalami, emi ki yio si ranti ẹ̀ṣẹ rẹ.

26 Rán mi leti: ki a jumọ sọ ọ; iwọ rò, ki a le da ọ lare.

27 Baba rẹ iṣãju ti ṣẹ̀, awọn olukọni rẹ ti yapa kuro lọdọ mi.

28 Nitorina mo ti sọ awọn olori ibi mimọ́ na di aimọ́, mo si ti fi Jakobu fun egún, ati Israeli fun ẹ̀gan.