Isa 28 YCE

Ìkìlọ̀ fún Ilẹ̀ Israẹli

1 EGBE ni fun ade igberaga, fun awọn ọmuti Efraimu, ati fun itàna rirọ ti ogo ẹwà rẹ̀, ti o wà lori afonifoji ọlọra ti awọn ti ọti-waini pa.

2 Kiye si i, Oluwa ni ẹnikan alagbara ati onipá, bi ẹfũfu lile, yiyin, ati ìji iparun, bi iṣàn-omi nla àkúnya, yio fi ọwọ́ bì ṣubu sori ilẹ.

3 Ade igberaga, awọn ọmuti Efraimu, li a o fi ẹsẹ tẹ̀ mọlẹ:

4 Ati ogo ẹwà, ti o wà lori afonifoji ọlọra, yio jẹ itanna rirọ, gẹgẹ bi eso ti o yara ṣaju igba ìkore; eyiti nigbati ẹniti o ba nwò o ba ri, nigbati o wà li ọwọ́ rẹ̀ sibẹ, o gbe e mì.

5 Li ọjọ na li Oluwa awọn ọmọ-ogun yio jẹ ade ogo, ati ade ẹwà fun iyokù awọn enia rẹ̀,

6 Ati ẹmi idajọ fun awọn ẹniti o joko ni idajọ, ati agbara fun awọn ti o le ogun padà si ibode.

Aisaya ati Àwọn Ọ̀mùtí Wolii Ilẹ̀ Juda

7 Ṣugbọn awọn pẹlu ti ti ipa ọti-waini ṣìna, ati nipa ọti-lile nwọn ti ṣako; alufa ati wolĩ ti ṣìna nipa ọti-lile, ọti-waini mu wọn daradara, nwọn di aṣako nipa ọti-lile, nwọn ṣìna ninu iran, nwọn kọsẹ ni idajọ.

8 Nitori gbogbo tabili li o kún fun ẽbi ati ẹgbin, kò si ibi ti o mọ́.

9 Tani on o kọ́ ni ìmọ? ati tani on o fi oye ẹkọ́ yé? awọn ẹniti a wọ́n li ẹnu-ọmú, ti a si já li ẹnu ọyàn.

10 Nitori aṣẹ le aṣẹ, aṣẹ le aṣẹ; ẹsẹ le ẹsẹ, ẹsẹ le ẹsẹ; diẹ nihin, diẹ lọhun:

11 Nitori nipa ète ẹlẹyà ati ni ède miran li on o fi bá enia wọnyi sọ̀rọ.

12 Si ẹniti on wipe, Eyi ni isimi, ẹnyin ìba mu awọn alãrẹ̀ simi; eyi si ni itura: sibẹ nwọn kì yio gbọ́.

13 Nitorina ọ̀rọ Oluwa jẹ aṣẹ le aṣẹ, aṣẹ le aṣẹ fun wọn: ẹsẹ le ẹsẹ, ẹsẹ le ẹsẹ; diẹ nihin, diẹ lọhun: ki nwọn ba le lọ, ki nwọn si ṣubu sẹhin, ki nwọn si ṣẹ́, ki a si dẹ wọn, ki a si mu wọn.

Òkúta Igun Ilé fún Sioni

14 Nitorina ẹ gbọ́ ọ̀rọ Oluwa, ẹnyin ẹlẹgàn, ti nṣe akoso awọn enia yi ti mbẹ ni Jerusalemu.

15 Nitori ẹnyin ti wipe, Awa ti ba ikú dá majẹmu, a si ti ba ipò-okú mulẹ: nigbati pàṣan gigun yio là a já, kì yio de ọdọ wa: nitori awa ti fi eké ṣe ãbo wa, ati labẹ irọ́ li awa ti fi ara wa pamọ:

16 Nitorina bayi li Oluwa Jehofah wi, pe, Kiyesi i, emi gbe okuta kan kalẹ ni Sioni fun ipilẹ, okuta ti a dán wò, okuta igun-ile iyebiye, ipilẹ ti o daju: ẹniti o gbagbọ kì yio sá.

17 Idajọ li emi o fi le ẹsẹ pẹlu, ati ododo li emi o fi lé òṣuwọn: yinyín yio gbá ãbo eke lọ, omi o si kún bò ibi isasi mọlẹ.

18 Majẹmu nyin ti ẹ ba ikú dá li a o sọ di asan, imulẹ nyin pẹlu ipò-okú kì yio duro; nigbati paṣán gigun yio rekọja; nigbana ni on o tẹ̀ nyin mọlẹ.

19 Niwọn igbati o ba jade lọ ni yio mu nyin: nitori ni gbogbo owurọ ni yio rekọja, li ọsan ati li oru: kiki igburo rẹ̀ yio si di ijaiyà.

20 Nitori akete kuru jù eyiti enia le nà ara rẹ̀ si, ati ìbora kò ni ibò to eyi ti on le fi bò ara rẹ̀.

21 Nitori Oluwa yio dide bi ti oke Perasimu, yio si binu gẹgẹ bi ti afonifoji Gibeoni, ki o ba le ṣe iṣẹ rẹ̀, iṣẹ àrà rẹ̀; yio si mu iṣe rẹ̀ ṣẹ, ajeji iṣe rẹ̀.

22 Njẹ nitorina, ẹ máṣe jẹ ẹlẹgàn, ki a má ba sọ ìde nyin di lile; nitori emi ti gbọ́ iparun lati ọdọ Oluwa, Oluwa awọn ọmọ-ogun wá, ti o ti pinnu lori gbogbo ilẹ.

Ọgbọ́n Ọlọrun

23 Ẹ fetisilẹ, ẹ si gbọ́ ohùn mi: ẹ tẹtilelẹ, ẹ si gbọ́ ọ̀rọ mi.

24 Gbogbo ọjọ ni agbẹ̀ ha nroko lati gbìn? on o ha ma tú, a si ma fọ́ ilẹ rẹ̀ bi?

25 Nigbati on ti tẹ́ ojú rẹ̀ tan, on kò ha nfunrugbìn dili, ki o si fọn irugbìn kummini ka, ki o si gbìn alikama lẹsẹ-ẹsẹ, ati barle ti a yàn, ati spelti nipò rẹ̀?

26 Nitori Ọlọrun rẹ̀ kọ́ ọ lati ni oye, o tilẹ kọ́ ọ.

27 Nitori a kò fi ohun-elò pakà dili, bẹ̃ni a kì iyí kẹkẹ́ kiri lori kummini; ṣugbọn ọpá li a ifi pa dili jade, ọgọ li a si fi lù kummini.

28 Akara agbado li a lọ̀; on kò le ma pa a titi, bẹ̃ni kò fi kẹkẹ́-ẹrù fọ́ ọ, bẹ̃ni kì ifi awọn ẹlẹṣin rẹ̀ tẹ̀ ẹ.

29 Eyi pẹlu ti ọdọ Oluwa awọn ọmọ-ogun wá, ẹniti o kún fun iyanu ni ìmọ, ti o tayọ ni iṣe.